ORIN 40
Ti Ta Ni A Jẹ́?
-
1. Ti ta ni ìwọ jẹ́?
Ọlọ́run wo ni ò ń sìn?
Ẹni tí o bá ń ṣègbọràn sí
L’ọlọ́run rẹ, tó ń darí rẹ.
Kò ṣeé ṣe láti sin
Ọlọ́run méjì pa pọ̀.
Ohun tó bá wà lọ́kàn rẹ ló máa
Pinnu èyí tó o máa yàn.
-
2. Ti ta ni ìwọ jẹ́?
Ọlọ́run wo ni ò ń sìn?
Ọ̀kan jẹ́ òótọ́, ọ̀kan jékèé.
Yan èyí tó o fẹ́ fúnra rẹ.
Ṣé Ọba ayé yìí
Lo ṣì ń fi ọkàn rẹ sìn?
Àbí wàá sin Ọlọ́run òtítọ́,
Kó o sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
-
3. Ti ta ni èmi jẹ́?
Jáà ni màá ṣègbọràn sí.
Bàbá mi ọ̀run lèmi yóò sìn.
Màá san gbogbo ẹ̀jẹ́ mi fún un.
Iye ńlá ló rà mí;
Tọkàntọkàn ni màá sìn ín.
Gbogbo ọjọ́ ayé mi ni màá fi
Gbé orúkọ ńlá rẹ̀ ga.
(Tún wo Jóṣ. 24:15; Sm. 116:14, 18; 2 Tím. 2:19.)