Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 43

Àdúrà Ìdúpẹ́

Àdúrà Ìdúpẹ́

(Sáàmù 95:2)

  1. 1. Bàbá aláàánú, jọ̀ọ́ gbọ́ àdúrà wa.

    Jèhófà, a dúpẹ́, a sì yìn ọ́.

    A gbẹ́kẹ̀ lé ọ, à ń sìn ọ́ látọkàn

    Torí a mọ̀ pé ò ń ṣìkẹ́ wa gan-an.

    Àìpé ń jẹ́ ká ṣàṣìṣe lójoojúmọ́.

    Jọ̀ọ́, dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.

    A dúpẹ́ gan-an pé o ti rà wá pa dà,

    Tó o sì tún mọ̀ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni wá.

  2. 2. A mọrírì ìfẹ́ àti àánú rẹ

    Àti bí o ṣe tún ń fà wá mọ́ra.

    Jẹ́ ká lè máa sìn ọ́, kọ́ wa ká mọ̀ ọ́,

    Ká jẹ́ olóòótọ́, ká dúró ṣinṣin.

    A dúpẹ́ pé ò ń fẹ̀mí rẹ darí wa.

    Ò ń fún wa nígboyà ká lè wàásù.

    A dúpẹ́ pé o máa ń ṣojúure sí wa.

    A ó máa fayọ̀ àtìrẹ̀lẹ̀ sìn ọ́.