Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 48

Máa Bá Jèhófà Rìn Lójoojúmọ́

Máa Bá Jèhófà Rìn Lójoojúmọ́

(Míkà 6:8)

  1. 1. Ní ojoojúmọ́ ayé wa,

    A ó máa fìrẹ̀lẹ̀ b’Ọ́lọ́run rìn.

    Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí

    Ló fún àwọn tó fẹ́ dọ̀rẹ́ rẹ̀.

    Ìfẹ́ ló mú kó fún wa ní

    Àǹfààní láti bá a rìn.

    Bá a ṣe yara wa sí mímọ́,

    Ká má fi Jèhófà sílẹ̀.

  2. 2. Lákòókò t’Èṣù ń bínú yìí,

    Tí òpin sì ń yára sún mọ́lé,

    À ń kojú inúnibíni

    Tó lè fẹ́ mú ká juwọ́ sílẹ̀.

    Àmọ́ Jáà máa ń dáàbò bò wá;

    Ká má kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

    Ká fi gbogbo ọkàn wa sìn ín,

    Ká jẹ́ adúróṣinṣin sí i.

  3. 3. Jèhófà máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀

    Àti ẹ̀mí rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́.

    Ó máa ń lo ìjọ Kristẹni,

    Ó sì tún máa ń gbọ́ àdúrà wa.

    Bí a ṣe ń bá Jèhófà rìn,

    Yóò mú ká ṣohun tó tọ́.

    Yóò mú ká lè dúró ṣinṣin,

    Ká sì máa fìrẹ̀lẹ̀ bá a rìn.