Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 51

A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!

A Ti Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run!

(Mátíù 16:24)

  1. 1. Ọlọ́run ló fà wá sọ́dọ̀ Jésù Kristi.

    A dọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ látòní.

    Jáà tan ìmọ́lẹ̀ òótọ́

    Láti orí ìtẹ́ rẹ̀.

    Ìgbàgbọ́ wa ń lágbára;

    A dé láti ṣèfẹ́ Jáà.

    (ÈGBÈ)

    A yàn láti yara wa sí mímọ́ fún Jáà.

    À ń yọ̀ torí a ní Jésù pẹ̀lú.

  2. 2. A gbàdúrà sí Jèhófà pé a ó máa sìnín.

    Aó máa gbọ́ràn sí i títí ayé.

    Ayọ̀ tí kò lẹ́gbẹ́ ni.

    À ń forúkọ Jáà pè wá.

    A ó fayọ̀ sọ fáráyé,

    A ó wàásù Ìjọba náà.

    (ÈGBÈ)

    A yàn láti yara wa sí mímọ́ fún Jáà.

    À ń yọ̀ torí a ní Jésù pẹ̀lú.