Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 59

Jẹ́ Ká Yin Jáà

Jẹ́ Ká Yin Jáà

(Sáàmù 146:2)

  1. 1. Jẹ́ ká yin Jáà;

    Ká kọrin sí i.

    Ó fún wa lẹ́mìí àtohun rere.

    Ojoojúmọ́

    Là ń fìyìn fún un.

    Alágbára ni, ìfẹ́ rẹ̀ pọ̀ gan-an.

    À ń kéde orúkọ rẹ̀ fáráyé.

  2. 2. Jẹ́ ká yin Jáà;

    Olùpèsè

    Tó ń gbọ́ àdúrà wa, tó ń tọ́jú wa.

    A ó máa ròyìn

    Agbára rẹ.

    Ò ń fún àwọn aláìlera lókun.

    Ò ń fẹ̀mí mímọ́ rẹ ràn wá lọ́wọ́.

  3. 3. Jẹ́ ká yin Jáà;

    Olóòótọ́ ni.

    Ó ńt ù wá nínú, a lè gbọ́kàn lé e.

    Ìjọba rẹ̀

    Yóò mú nǹkan tọ́.

    Yóò mú ìtura bá gbogbo ayé.

    Ẹ jẹ́ ká fayọ̀ àt’ìtara yìn ín.