Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 61

Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí

Ẹ Tẹ̀ Síwájú, Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí

(Lúùkù 16:16)

  1. 1. Àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti pinnu

    Láti máa fìgboyà wàásù lákòókò yìí.

    Èṣù ń ta kò wá, ó sì ńgbógun.

    Àmọ́, a dúró ṣinṣin ti Jèhófà.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà.

    Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́.

    Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán.

    Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa.

  2. 2. Ìránṣẹ́ Jáà, má ṣe gbé ayé fàájì.

    Ṣọ́ra fún ìfẹ́ ayé, má ṣe bíi tiwọn.

    Má jẹ́ kí wọ́n kó èérí bá ọ.

    Jẹ́ adúróṣinṣin títí dé òpin.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà.

    Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́.

    Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán.

    Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa.

  3. 3. Wọ́n ń pẹ̀gàn Ọlọ́run àt’Ìjọba rẹ̀.

    Wọ́n ń bà á lórúkọ jẹ́, wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ láìdáa.

    Ká jẹ́ kórúkọ rẹ̀ di mímọ́.

    Ẹ jẹ́ ká kéde rẹ̀ fún gbogbo ayé.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ tẹ̀ síwájú, Ẹlẹ́rìí onígboyà.

    Ẹ máa yọ̀ pé ẹ̀ ń bá Ọlọ́run wa ṣiṣẹ́.

    Ẹ sọ fáráyé pé Párádísè dé tán.

    Ìjọba Ọlọ́run yóò bù kún wa.