ORIN 63
Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ni Wá
-
1. Àwọn èèyàn ń bọ̀rìṣà
Wọn kò m’Ọlọ́run tòótọ́.
Olódùmarè ni;
Iṣẹ́ rẹ̀ ń fi hàn.
Àwọn ọlọ́run èké
Kò lè mọ ọjọ́ ọ̀la.
Kò sí ẹlẹ́rìí kankan fún wọn.
Wọ́n kéré sí Ọlọ́run wa.
(ÈGBÈ)
Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.
À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù.
Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;
Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ.
-
2. À ń kéde orúkọ rẹ̀.
À ń jẹ́rìí rẹ̀ fáráyé.
À ń fìgboyà wàásù
Nípa ‘jọba rẹ̀.
À ń jẹ́ kọ́pọ̀ èèyàn mọ
Bóòótọ́ ṣe ń túni sílẹ̀.
Bá a ṣe ń kọ́ wọn, ó ńwọ̀ wọ́n lọ́kàn.
Àwọn náà wá ń yin Ọlọ́run.
(ÈGBÈ)
Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.
À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù.
Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;
Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ.
-
3. Bá a ṣe ńgbórúkọ rẹ̀ ga
Ń mú kí ẹ̀gàn rẹ̀ kúrò.
À ń kìlọ̀ fẹ́ni ‘bi
Tó ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn.
Ṣùgbọ́n tó bá yí pa dà,
Jọ̀wọ́ Bàbá, dárí jì í.
Bí a ṣe ń sìn ọ́ látọkàn wá,
À ń láyọ̀, a sì nírètí.
(ÈGBÈ)
Ẹlẹ́rìí Jáà ni àwa.
À ń wàásù lọ láìbẹ̀rù.
Ọlọ́run wa ń sọ àsọtẹ́lẹ̀;
Gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ń ṣẹ.
((Tún wo Àìsá. 37:19; 55:11; Ìsík. 3:19.)