Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 72

À Ń Kéde Òtítọ́ Ìjọba Náà

À Ń Kéde Òtítọ́ Ìjọba Náà

(Ìṣe 20:20, 21)

  1. 1. Ìgbà kan wà tí a kò mọ

    Ọ̀nà tó yẹ kí a máa rìn.

    Jèhófà tan ìmọ́lẹ̀

    Òótọ́ Ìjọba rẹ̀ fún wa.

    A wá ríi pé Jèhófà fẹ́

    Ká kọ́wọ́ ti Ìjọba rẹ̀.

    Ká kéde rẹ̀ fáráyé,

    Ká sì tún gbórúkọ mímọ́ rẹ̀ ga.

    À ńwàásù fún gbogbo èèyàn

    Nílé délé, lójú ọ̀nà.

    À ńkọ́ wọn ní ẹ̀kọ́ òótọ́

    Tó ńsọni di òmìnira.

    À ńsapá ní gbogbo ayé

    Káwọn tó ńsin Jáà lè pọ̀ síi.

    Ká máa ṣiṣẹ́ níṣọ̀kan

    Títí Jèhófà yóò sọ pé ó tó.