Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 74

Jẹ́ Ká Jọ Kọ Orin Ìjọba Náà

Jẹ́ Ká Jọ Kọ Orin Ìjọba Náà

(Sáàmù 98:1)

  1. 1. Orin ayọ̀ ìṣẹ́gun ni orin yìí.

    Ó ń gbé Olódùmarè Ọba ga.

    Jẹ́ ká jọ kọ ọ́; ó ń fún wa ní ìrètí,

    Ó sì ń kọ́ wa pé ká dúró ṣinṣin.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ wọlé wá síwájú Jáà.

    Ẹ kéde pé Jésù lọba.

    Mọ orin yìí, orin nípa ‘jọba náà.

    Wá jọ́sìn Jáà, kó o yin orúkọ rẹ̀.

  2. 2. À ń forin tuntun yìí kéde fáráyé

    Pé Jésù Kristi ti ń jọba lọ́run.

    Àwọn kan wà tó máa bá Jésù jọba.

    Ọlọ́run ti sọ wọ́n di àtúnbí.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ wọlé wá síwájú Jáà.

    Ẹ kéde pé Jésù lọba.

    Mọ orin yìí, orin nípa ‘jọba náà.

    Wá jọ́sìn Jáà, kó o yin orúkọ rẹ̀.

  3. 3. Àwọn onírẹ̀lẹ̀ lè mọ orin yìí.

    Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọrùn, ó sì dùn mọ́ni.

    Ọ̀pọ̀ ti mọ orin yìí kárí ayé,

    Wọ́n sì tún ń ké sí àwọn mìíràn pé:

    (ÈGBÈ)

    Ẹ wọlé wá síwájú Jáà.

    Ẹ kéde pé Jésù lọba.

    Mọ orin yìí, orin nípa ‘jọba náà.

    Wá jọ́sìn Jáà, kó o yin orúkọ rẹ̀.