Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 78

‘Máa Kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’

‘Máa Kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run’

(Ìṣe 18:11)

  1. 1. Àǹfààní ńlá la ní láti

    Kọ́ni lọ́r’Ọlọ́run.

    Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí,

    Ó máa ń dùn mọ́ni gan-an.

    Bí a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn

    Lẹ́kọ̀ọ́ ọ̀r’Ọlọ́run,

    À ń ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa

    Sún mọ́ Ọlọ́run wa.

  2. 2. Àwa náà gbọ́dọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́

    Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa;

    Ká sì jẹ́ kó máa hàn nínú

    Ìgbésí ayé wa,

    Káwọn ẹlòmíràn lè rí

    Ìwà rere wa yìí.

    Bí a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn yìí

    Là ń kọ́ ara wa náà.

  3. 3. Jèhófà ti pèsè àwọn

    Ohun tá a máa nílò.

    Àdúrà ń kópa pàtàkì

    Ká lè ṣàṣeyọrí.

    A mọ̀ dájú pé Jèhófà

    Máa gbọ́ àdúrà wa.

    Láìpẹ́, àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ náà

    Máa lè kọ́ àwọn mí ì!