ORIN 81
Ìgbésí Ayé Àwọn Aṣáájú-Ọ̀nà
-
1. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, tí oòrùn kò tí ì yọ,
Ọkàn wa wà níbi
iṣẹ́ Jáà tá a pinnu láti ṣe.
À ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fáyé, pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́;
Àwọn kan ń gbọ́rọ̀ wa,
báwọn kan kò tiẹ̀ wobi tá a wà.
(ÈGBÈ)
Iṣẹ́ tá a yàn nìyí,
Ìfẹ́ Jáà la fẹ́ ṣe.
Ohun tó fẹ́ ká ṣe la ó máa ṣe.
Bóòrùn ń ràn, bójò ń rọ̀,
Kò ṣèdíwọ́ fún wa.
Èyí la fi ń fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
-
2. Nígbà tílẹ̀ bá ṣú, tá a bojú wẹ̀yìn wò,
bó tiẹ̀ lè ti rẹ̀ wá,
Inú wa ń dùn, a sì ń gbàdúrà.
Jèhófà ń bù kún wa lójoojúmọ́ ayé.
À ń sun oorun ayọ̀,
à ń jí sáyé, a fọpẹ́ fún Jáà.
(ÈGBÈ)
Iṣẹ́ tá a yàn nìyí,
Ìfẹ́ Jáà la fẹ́ ṣe.
Ohun tó fẹ́ ká ṣe lá ó máa ṣe.
Bóòrùn ń ràn, bójò ń rọ̀,
Kò ṣèdíwọ́ fún wa.
Èyí la fi ń fi hàn pá a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà.
(Tún wo Jóṣ. 24:15; Sm. 92:2; Róòmù 14:8.)