ORIN 85
Ẹ Fayọ̀ Tẹ́wọ́ Gba Ara Yín
-
1. A kí yín káàbọ̀ sí Gbọ̀ngàn ‘jọba,
Gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ wá jọ́sìn Jáà.
Ìpèsè oúnjẹ tẹ̀mí wà fún wa;
Ìpéjọ wa ládùn, ó lóyin, à ń kẹ́kọ̀ọ́.
-
2. A mọrírì àwọn arákùnrin
Tó ń múpò ‘wájú nínú ìjọ.
Ẹni ọ̀wọ́n tí Jáà fún wa ni wọ́n,
Bí wọ́n ṣe ń bójú tó iṣẹ́ táa yàn fún wọn.
-
3. À ń ké sí gbogbo orílẹ̀-èdè
Kí wọ́n lè wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Jèhófà àti Jésù ló ń fà wá;
Ká fi tọkàntọkàn tẹ́wọ́ gba ara wa.
(Tún wo Jòh. 6:44; Fílí. 2:29; Ìfi. 22:17.)