Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 86

A Gbọ́dọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà

A Gbọ́dọ̀ Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Jèhófà

(Àìsáyà 50:4; 54:13)

  1. 1. Jèhófà ń ké sí gbogbo wa ká wá kẹ́kọ̀ọ́.

    Ẹ̀mí àtìyàwó ń sọ pé: “Máa bọ̀.”

    Àtìgbàdégbà l’Ọlọ́run ń kọ́ wa

    Kí àlàáfíà wa lè pọ̀ yanturu.

  2. 2. Ó yẹ ká máa wá sípàdé ìjọ déédéé

    Ká lè máa kẹ́kọ̀ọ́, ká ṣohun tó tọ́.

    Ìpàdé wa yìí ń mú ká nígbàgbọ́,

    Ẹ̀mí Ọlọ́run ló sì ń darí rẹ̀.

  3. 3. Inú wa ńdùn bá a ṣe ń gbọ́ tí àwọn ará

    Ń fayọ̀ kọrin ìyìn ní ìpàdé.

    Ká máa pàdé pọ̀ pẹ̀láwọn ará,

    Ká lè máa fìfẹ́ gbé ara wa ró!