Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 87

Ẹ Wá Gba Ìtura

Ẹ Wá Gba Ìtura

(Hébérù 10:24, 25)

  1. 1. Ayé Sátánì tá à ń gbé yìí burú gan-an;

    A nílò ẹ̀kọ́ Ọlọ́run.

    Torí kò sí ohun tí a lè dá ṣe,

    Àfi ká rí ìtọ́sọ́nà.

    Àwọn ìpàdé wa máa ń tuni lára;

    Wọ́n ń jẹ́ ká túbọ̀ nírètí.

    Wọ́n ń mú kígbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára,

    Wọ́n sì máa ń fún wa níṣìírí.

    A ó máa rí i pé à ń wá sípàdé déédéé

    Ká lè múnú Jèhófà dùn.

    A gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n lo àkókò wa;

    Ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí.

  2. 2. Jèhófà mọ àwọn ohun tá a nílò,

    Ó sì ti pèsè wọn fún wa.

    Ẹrú olóòótọ́ àtàwọn alàgbà;

    Wọ́n ń fún wa nítọ̀ọ́ni tó dáa.

    Tá a bá ń tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n ń fún wa,

    Yóò ṣe wá lọ́pọ̀ àǹfààní.

    Ẹgbẹ́ ará kárí ayé wà níbẹ̀,

    Gbogbo wa nífẹ̀ẹ́ ara wa.

    Ṣe ni ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ ń lágbára,

    A kò bẹ̀rù, a kò jáyà.

    A ó máa rí i pé à ń wá sípàdé déédéé

    Bá a ṣe ń retí ayé tuntun.