ORIN 89
Gbọ́, Ṣègbọràn, Kó O sì Gba Ìbùkún
-
1. Aláyọ̀ làwọn tó ń gbọ́rọ̀ Ọlọ́run,
Tí wọ́n ń fetí sẹ́kọ̀ọ́ Jésù Kristi;
Ìbàlẹ̀ ọkàn, ìdùnnú, àlàáfíà,
Yóò jẹ́ tàwọn tó bá jónígbọràn.
(ÈGBÈ)
Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún,
Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀.
Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn,
Ìgbọràn ṣe pàtàkì.
-
2. Tá a bá jẹ́ onígbọràn sí Ọlọ́run,
Ìgbésí ayé wa yóò dára gan-an.
Ó máa dà bí ilé orí àpáta
Tó lágbára, tó sì fìdí múlẹ̀.
(ÈGBÈ)
Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún,
Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀.
Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn,
Ìgbọràn ṣe pàtàkì.
-
3. Tí a bá fetí sí ohùn Jèhófà,
Tá à ń tẹ̀ lé àṣẹ àti ‘lànà rẹ̀,
A máa dà bí igi tá a gbìn sétídò,
Tó ń so èso rẹ̀ lákòókò tó yẹ.
(ÈGBÈ)
Gbọ́, ṣègbọràn, gbàbùkún,
Tí Ọlọ́run bá ń sọ̀rọ̀.
Tó o bá fẹ́ máa múnú Jèhófà dùn,
Ìgbọràn ṣe pàtàkì.
(Tún wo Diu. 28:2; Sm. 1:3; Òwe 10:22; Mát. 7:24-27; Lúùkù 6:47-49.)