ORIN 95
Ìmọ́lẹ̀ Náà Ń Mọ́lẹ̀ Sí I
(Òwe 4:18)
-
1. Àwọn wòlíì àtijọ́ fẹ́ mọ Kristi,
Ẹni tó jẹ́ káyé nírètí.
Ẹ̀mí Ọlọ́run jẹ́rìí sí i pé yóò wá,
Yóò jẹ́ káráyé rítùúsílẹ̀.
Ní báyìí, Mèsáyà ti ń jọba lọ́run,
Ẹ̀rí tó dájú fèyí hàn.
Àǹfààní ló jẹ́ láti m’òtítọ́ yìí,
Òótọ́ táwọn áńgẹ́lì fẹ́ mọ̀!
(ÈGBÈ)
Ipa ọ̀nà wa ti ń mọ́lẹ̀ sí i
Bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gangan.
Ọlọ́run ń ṣí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá;
Ó ń tọ́ wa sọ́nà tá ó máa rìn.
-
2. Ẹrú olóòótọ́ tí Jésù yàn sípò,
Ń fún wa lóúnjẹ lákòókò tó yẹ.
Ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ló ń fa olóòótọ́ ọkàn mọ́ra.
Ìmọ́lẹ̀ túbọ̀ ń tàn sípa ọ̀nà wa,
Ẹsẹ̀ wa kò kúrò lọ́nà.
A dúpẹ́, Jèhófà, Orísun ‘mọ́lẹ̀,
Títí láé la ó máa rìn lọ́nà rẹ.
(ÈGBÈ)
Ipa ọ̀nà wa ti ń mọ́lẹ̀ sí i
Bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán gangan.
Ọlọ́run ń ṣí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá;
Ó ń tọ́ wa sọ́nà tá ó máa rìn.
(Tún wo Róòmù 8:22; 1 Kọ́r. 2:10; 1 Pét. 1:12.)