Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 100

Máa Fi Ìfẹ́ Gbà Wọ́n Lálejò

Máa Fi Ìfẹ́ Gbà Wọ́n Lálejò

(Ìṣe 17:7)

  1. 1. Jèhófà máa ń fìfẹ́ tọ́jú gbogbo wa.

    Ó máa ń fìfẹ́ pèsè fún gbogbo èèyàn.

    Ó ń mú kí oòrùn ràn,

    Ó ńmú kí òjò rọ̀;

    Ó ń fún wa ní oúnjẹ tó dára.

    Ó yẹ káwa náà fara wé Ọlọ́run.

    Ká máa ṣàánú àwọn tó jẹ́ aláìní.

    Ká máa ràn wọ́n lọ́wọ́,

    Kí ara lè tù wọ́n.

    Ká rí i pé a ṣeé látọkàn wá.

  2. 2. Ẹ jẹ́ ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Lìdíà

    Tó gba àwọn ẹni mímọ́ lálejò.

    Ẹ̀mí ọ̀làwọ́ wa

    Àtìfẹ́ tá a ń fi hàn

    Yóò fògo fún Bàbá wa ọ̀run.

    Tí àwọn àlejò bá wá sọ́dọ̀ wá,

    Ẹ jẹ́ ká fìfẹ́ gbà wọ́n sínú ‘lé wa.

    Bàbá wa onífẹ̀ẹ́

    Rí gbogbo ‘hun tá à ń ṣe.

    Ó dájú pé yóò pín wa lérè.