Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 103

Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

Ẹ̀bùn Ni Àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn

(Éfésù 4:8)

  1. 1. Jáà fún wa ní àwọn ọkùnrin;

    Ẹ̀bùn nínú èèyàn.

    Wọ́n ń fàpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀;

    Wọ́n máa ń tọ́ wa sọ́nà.

    (ÈGBÈ)

    Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́

    Ni Ọlọ́run yàn fún wa

    Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀;

    Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn.

  2. 2. Àwọn olùṣọ́ àgùntàn wa

    Kì í fọ̀rọ̀ wa ṣeré.

    Tí ìṣòro bá sì dé bá wa,

    Wọ́n máa ń bójú tó wa.

    (ÈGBÈ)

    Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́

    Ni Ọlọ́run yàn fún wa

    Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀;

    Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn.

  3. 3. Wọ́n máa ń gbà wá nímọ̀ràn tó dáa

    Ká lè ṣohun tó tọ́.

    Wọ́n máa ń pèsè ‘rànwọ́ tá a nílò

    Ká lè máa jọ́sìn Jáà.

    (ÈGBÈ)

    Àwọn ọkùnrin tó jólóòótọ́

    Ni Ọlọ́run yàn fún wa

    Láti máa bójú tó ìjọ rẹ̀;

Ẹ jẹ́ ká máa nífẹ̀ẹ́ wọn.