ORIN 106
Bá A Ṣe Lè Ní Ìfẹ́
-
1. À ń gbàdúrà s’Ọ́lọ́run wa pé
Ká lè f’ànímọ́ rẹ̀ ṣèwà hù.
Ìfẹ́ ló gbawájú nínú wọn;
Ẹ̀mí mímọ́ máa jẹ́ ká nífẹ̀ẹ́.
Bá a tiẹ̀ lẹ́bùn, tá a sì nígboyà,
Tá a nímọ̀, àmọ́ tá a kò nífẹ̀ẹ́,
Asán ni gbogbo ẹ̀bùn náà jẹ́.
Torí náà, kífẹ̀ẹ́ máa darí wa.
-
2. Ìfẹ́ máa ń fúnni látọkàn wá.
Ìfẹ́ kì í mọ tara rẹ̀ nìkan.
Kì í fàyè gba èrò tí kò dáa;
Ó ń mú ká máa dárí jira wa.
Ìfẹ́ ń fara da ohun gbogbo;
Ó ń jẹ́ ká lè gbẹ́rù tó wúwo.
Ká fìfẹ́ hàn ní gbogbo ọ̀nà;
Ìfẹ́ tòótọ́ kò ní yẹ̀ láéláé.
(Tún wo Jòh. 21:17; 1 Kọ́r. 13:13; Gál. 6:2.)