ORIN 109
Ní Ìfẹ́ Tó Ti Ọkàn Wá
-
1. Jèhófà lorísun ìfẹ́.
Bí a bá ń fẹ́ni látọkàn,
A ó mú ọkàn rẹ̀ yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀;
Ìyẹn ṣeyebíye.
Bíjì bá ń jà, tílé sì ńjó,
Ìfẹ́ ará wa ń gbèrú sí i.
A kò ní fi wọ́n sílẹ̀ láé;
A nífẹ̀ẹ́ wọn dọ́kàn.
Bí a bá ń báni kẹ́dùn,
T áa fúnni lókun nígbà ‘ṣòro,
Ọ̀rẹ́ àìṣẹ̀tàn nìyẹn,
Elétí bánigbọ́rọ̀.
Bí Jésù sì ṣe nífẹ̀ẹ́ wa
Fi ànímọ́ Jèhófà hàn.
Àwa náà lè máa fìfẹ́ hàn
Lọ́nà tó dára jù lọ;
Ká nífẹ̀ẹ́ látọkàn wá.
(Tún wo 1 Pét. 2:17; 3:8; 4:8; 1 Jòh 3:11.)