Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 114

Ẹ Máa Ní Sùúrù

Ẹ Máa Ní Sùúrù

(Jémíìsì 5:8)

  1. 1. Jèhófà Ọlọ́run wa

    Nítara f’óókọ mímọ́ rẹ̀.

    Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni pé

    Kí orúkọ rẹ̀ jẹ́ mímọ́.

    Ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà

    Ti ń fara da ọ̀pọ̀ nǹkan.

    Ó ń finúure hàn sí wa;

    Ó ń fìfẹ́ ní sùúrù.

    Ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ni pé

    Kí ọ̀pọ̀ èèyàn rígbàlà.

    Sùúrù tí Jèhófà ní

    Látọjọ́ yìí kò já sásán.

  2. 2. Tá a bá jẹ́ onísùúrù,

    Ó máa tọ́ wa sọ́nà tó dáa.

    Ó máa fọkàn wa balẹ̀.

    Kò ní jẹ́ ká bínú sódì.

    Kò ní jẹ́ kí a máa ṣọ́

    Àṣìṣe àwọn mìíràn.

    Yóò jẹ́ ká nífaradà

    Bí a tiẹ̀ níṣòro.

    Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run

    Yóò jẹ́ ká lè máa ní sùúrù.

    Tá a bá jẹ́ onísùúrù,

    A máa fìwà jọ Ọlọ́run.