Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 117

Ìwà Rere

Ìwà Rere

(2 Kíróníkà 6:41)

  1. 1. Jèhófà, Ẹniire ni ọ́;

    Adúróṣinṣin ni ọ́.

    Ìgbà gbogbo lò ń bù kún wa;

    Gbogbo ọ̀nà rẹ ló dáa.

    O máa ń fojúure hàn sí wa

    Bí a tiẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.

    Ìwọ nìkan lògo tọ́ sí;

    Aó máa fayọ̀ jọ́sìn rẹ.

  2. 2. Àwa tá a jẹ́ ènìyàn rẹ

    Ńfara wé inúure rẹ.

    Ó máa ń hàn nínú ìwà wa

    Àtiṣẹ́ ‘wàásù tá à ńṣe.

    Ẹ̀kọ́ rẹ ń ṣe wá láǹfààní,

    Ó ń sèso kárí ayé.

    Jọ̀ọ́, fún wa lẹ́mìí mímọ́ rẹ

    Ká lè máa hùwà rere.

  3. 3. Jọ̀wọ́, bù kún wa Jèhófà

    Bí a ṣe ń hùwà rere

    Sáwọn ará níbi gbogbo,

    Lọ́kùnrin àtobìnrin.

    Fi ẹ̀mí rẹ ràn wá lọ́wọ́

    Ká lè máa hùwà rere

    Nínú ilé, nínú ìjọ,

    Ládùúgbò, níbi gbogbo.