Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 120

Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi

Jẹ́ Oníwà Tútù Bíi Kristi

(Mátíù 11:28-30)

  1. 1. Jésù lẹni tó tóbi jù lọ láyé.

    Ìgbéraga kò sí nínú ìwà rẹ̀.

    Ipò ńlá ni Jèhófà fi Jésù sí.

    Síbẹ̀, onírẹ̀lẹ̀ ni látọkàn wá.

  2. 2. Gbogbo àwọn tó ní ìdààmú ọkàn,

  3. Jésù ṣe tán láti bá wọn gbẹ́rù wọn.

    Àwọn oníwà tútù yóò rítura

    Bí wọ́n ṣe ń wá ire Ìjọba ọ̀run.

  4. 3. Jésù sọ pé ará ni gbogbo wa jẹ́.

    Òun ni Orí wa, àṣẹ rẹ̀ là ń tẹ̀ lé.

  5. Ọlọ́run mọyì àwọn onírẹ̀lẹ̀.

    Ó ṣèlérí pé wọ́n máa jogún ayé.