Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 123

Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

Máa Ṣègbọràn sí Ètò Ọlọ́run

(1 Kọ́ríńtì 14:33)

  1. 1. Báwa èèyàn Jáà ṣe ń kéde òtítọ́

    Nípa Ìjọba náà káàkiri ayé,

    Ó yẹ ká ṣègbọràn sétò Ọlọ́run.

    Ká wà ní ìṣọ̀kan, ká jẹ́ olóòótọ́.

    (ÈGBÈ)

    Tá a bá ń ṣègbọràn sétò Ọlọ́run,

    Jèhófà máa láyọ̀.

    Yóò dáàbò bò wá, yóò sì pa wá mọ́

    Bá a ṣe ń jẹ́ olóòótọ́ sí i.

  2. 2. Ẹ̀mí mímọ́ àti ẹrú olóòótọ́;

    Wọn yóò máa tọ́ wa sọ́nà ìyè tòótọ́.

    Torí náà ká wá ojúure Ọlọ́run;

    Ká dúró ṣinṣin, ká kéde rẹ̀ fáyé.

    (ÈGBÈ)

    Tá a bá ń ṣègbọràn sétò Ọlọ́run,

    Jèhófà máa láyọ̀.

    Yóò dáàbò bò wá, yóò sì pa wá mọ́

    Bá a ṣe ń jẹ́ olóòótọ́ sí i.