ORIN 124
Jẹ́ Adúróṣinṣin
-
1. Dúró ṣinṣin sí Jèhófà,
Kó o sì jẹ́ olóòótọ́ sí i.
A ti yara wa sí mímọ́;
Àṣẹ rẹ̀ la fẹ́ pa mọ́.
Tá a bá ń ṣègbọràn sọ́rọ̀ rẹ̀,
Ó máa ṣe wá láǹfààní.
Ká gbẹ́kẹ̀ lé e; olóòótọ́ ni.
Má ṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
-
2. Dúró ṣinṣin sáwọn ará
Ní àkókò ìṣòro.
Ká máa kẹ́ wọn, ká gbé wọn ró,
Ká sì sọ̀rọ̀ tó tura.
Ká máa bọlá fáwọn ará;
Bọ̀wọ̀ fún wọn látọkàn.
Ká rí i pé à ń dúró tì wọ́n;
Ká má fi wọ́n sílẹ̀ láé.
-
3. Dúró ṣinṣin, gba ìmọ̀ràn
Àwọn tó ń múpò ‘wájú
Tí wọ́n bá ti ń tọ́ wa sọ́nà;
Ká gbọ́ràn tọkàntọkàn.
Jèhófà yóò sì bù kún wa,
Yóò sọ wá d’alágbára.
Tá a bá jẹ́ adúróṣinṣin,
Ti Jèhófà la ó máa jẹ́.
(Tún wo Sm. 149:1; 1 Tím. 2:8; Héb. 13:17.)