ORIN 131
Ohun Tí Ọlọ́run So Pọ̀
-
1. Jáà fìfẹ́ so wọ́n pọ̀;
Ọkàn wọn kún fáyọ̀.
Àwọn èèyàn jẹ́rìí sí i,
Bí wọ́n ṣe ń jẹ́jẹ̀ẹ́ wọn.
(ÈGBÈ 1)
Ọkọ jẹ́jẹ̀ẹ́ fáya pé:
‘Màá fẹ́ ọ látọkàn.’
‘Ohun t’Ọlọ́run so pọ̀,
Kéèyàn má ṣe yà wọ́n.’
-
2. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
Kí wọ́n lè ṣèfẹ́ Jáà.
Wọ́n ńbẹ̀bẹ̀ fún ‘rànwọ́ rẹ̀
Láti mẹ́jẹ̀ẹ́ wọn ṣẹ.
(ÈGBÈ 2)
Aya jẹ́jẹ̀ẹ́ fọ́kọ pé:
Màá fẹ́ ọ látọkàn.’
‘Ohun t’Ọlọ́run so pọ̀,
Kéèyàn má ṣe yà wọ́n.’
(Tún wo Jẹ́n. 2:24; Oníw. 4:12; Éfé. 5:22-33.)