Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 135

Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”

Jèhófà Fìfẹ́ Rọ̀ Ọ́ Pé: “Ọmọ Mi, Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n”

(Òwe 27:11)

  1. 1. Ọ̀dọ́kùnrin, ọ̀dọ́bìnrin,

    Múnú mi dùn.

    Jẹ́ kígbèésí ayé

    Rẹ bá ìfẹ́ mi mu.

    Kó o lo àkókò ọ̀dọ́

    Rẹ pẹ̀lú ọgbọ́n,

    Kó o lè dójú tọ̀tá

    Tó ń gan orúkọ mi.

    (ÈGBÈ)

    Àyànfẹ́ ọmọ mi ọkùnrin,

    Àtolùfẹ́ ọmọbìnrin;

    Jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kó o sì fi

    Ìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo.

  2. 2. Máa fi ayọ̀ ṣe ìfẹ́ mi

    Látọkàn wá.

    Jẹ́ kí àwọn èèyàn

    Mọ̀ pé tèmi ni ọ́.

    Ẹni fọwọ́ kàn ẹ́

    Ń wá ojú pípọ́n mi,

    Bó o bá tiẹ̀ ṣubú,

    Èmi yóò gbé ọ dìde.

    (ÈGBÈ)

    Àyànfẹ́ ọmọ mi ọkùnrin,

    Àtolùfẹ́ ọmọbìnrin;

    Jẹ́ ọlọ́gbọ́n ọmọ, kó o sì fi

    Ìgbésẹ̀ rẹ yìn mí lógo.