Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 137

Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa

Àwọn Obìnrin Olóòótọ́, Àwọn Arábìnrin Wa

(Róòmù 16:2)

  1. 1. A ní àwọn obìnrin tó jólóòótọ́.

    Lára wọn ni Sérà, Ẹ́sítà, Rúùtù.

    Màríà kò gbẹ́yìn; wọ́n fọkàn sin Jáà.

    Adúróṣinṣin làwọn obìnrin yìí.

    Ọ̀pọ̀ ló wà tá ò morúkọ wọn,

    Àmọ́ ìgbàgbọ́ wọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa.

  2. 2. Àwọn ànímọ́ tó dáa táráyé ń fẹ́—

    Ìṣòtítọ́, ìgboyà, inú rere,

    Làwọn obìnrin dáadáa wọ̀nyí gbé yọ.

    Wọ́n jẹ́ àwòkọ́ṣe tó dára fún wa.

    Lónìí náà, àwọn arábìnrin wa

    Jẹ́ adúróṣinṣin, a sì mọyì wọn gan-an.

  3. 3. Gbogbo ẹ̀yin arábìnrin wa ọ̀wọ́n,

    Tẹ́ ẹ ń fìdùnnú ṣiṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.

    Onírẹ̀lẹ̀ ni yín, ẹ máa ń tẹrí ba.

    Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ yín, ẹ má ṣe bẹ̀rù.

    Jèhófà kò ní fi yín sílẹ̀ láé;

    Ẹ fọkàn yín balẹ̀, èrè yín ti dé tán!