ORIN 138
Ẹwà Orí Ewú
-
1. A ní àwọn tó dàgbà
Ní ọjọ́ orí.
Wọ́n fara da ọ̀pọ̀ nǹkan
Nígbà ọ̀dọ́ wọn.
Àwọn kan ti pàdánù
Ẹnì kejì wọn.
Wọn kò lókun tó pọ̀ mọ́,
Wọ́n sì jólóòótọ́.
(ÈGBÈ)
Bàbá, jọ̀ọ́ kà wọ́n yẹ,
Jọ̀wọ́, rántí wọn.
Mú kí wọ́n gbóhùn rẹ
Pé, “O káre láé!”
-
2. Ẹwà ni orí ewú
Lọ́nà òdodo.
Àwọn tó jẹ́ olóòótọ́
Jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n.
Ó yẹ káwa náà mọ̀ pé
Wọ́n ti ṣọ̀dọ́ rí.
Ẹni tó rẹwà ni wọ́n
Lójú Jèhófà.
(ÈGBÈ)
Bàbá, jọ̀ọ́ kà wọ́n yẹ,
Jọ̀wọ́, rántí wọn.
Mú kí wọ́n gbóhùn rẹ
Pé, “O káre láé!”
(Tún wo Sm. 71:9, 18; Òwe 20:29; Mát. 25:21, 23; Lúùkù 22:28; 1 Tím. 5:1.)