Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 141

Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́

Ìyanu Ni Ìwàláàyè Jẹ́

(Sáàmù 36:9)

  1. 1. Ọmọ jòjòló, ọ̀wààrà òjò,

    Ìmọ́lẹ̀ oòrùn àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ;

    Gbogbo wọn ló jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run.

    Wọ́n jẹ́rìí síṣẹ́ ìyanu ojoojúmọ́.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ̀bùn yìí ṣọ̀wọ́n ó sì ṣeyebíye.

    Báwo la ṣe lè fi hàn pá a mọyì ẹ̀bùn yìí?

    Ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká fìmọrírì hàn;

    Ẹ̀bùn ìyanu ńlá ni ìwàláàyè jẹ́.

  2. 2. Àwa kò gbọ́dọ̀ juwọ́ sílẹ̀ láé,

    Bíi taya Jóòbù tó sọ fọ́kọ rẹ̀ pé:

    ‘Bú Ọlọ́run rẹ, ṣe tán láti kú.’

    Àwa yóò máa yin Ọlọ́run wa títí láé.

    (ÈGBÈ)

    Ẹ̀bùn yìí ṣọ̀wọ́n ó sì ṣeyebíye.

    Báwo la ṣe lè fi hàn pá a mọyì ẹ̀bùn yìí?

    Ká nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ká fìmọrírì hàn;

    Ẹ̀bùn ìyanu ńlá ni ìwàláàyè jẹ́.