Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORÍ 14

“Òfin Tẹ́ńpìlì Náà Nìyí”

“Òfin Tẹ́ńpìlì Náà Nìyí”

ÌSÍKÍẸ́LÌ 43:12

OHUN TÍ ORÍ YÌÍ DÁ LÉ: Ohun tí ìran tẹ́ńpìlì náà kọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run nígbà ayé Ìsíkíẹ́lì àti lóde òní

1, 2. (a) Nínú orí tó ṣáájú, kí la rí kọ́ nípa ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí? (b) Ìbéèrè méjì wo la máa gbé yẹ̀ wò nínú orí yìí?

 NÍNÚ orí tó ṣáájú, a kẹ́kọ̀ọ́ pé kì í ṣe tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún ni Ìsíkíẹ́lì rí. A tún kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà fi ìran yẹn han wòlíì náà kó lè kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ nípa bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé ìlànà rẹ̀ nínú ìjọsìn wọn. Àfi tí wọ́n bá tẹ̀ lé ìlànà yẹn nìkan ni wọ́n á tó lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Èyí jẹ́ ká rí ìdí tí Jèhófà fi tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́ẹ̀mejì nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣoṣo, ọ̀rọ̀ náà sì ni: “Òfin tẹ́ńpìlì náà nìyí.”​—Ka Ìsíkíẹ́lì 43:12.

2 Ẹ jẹ́ ká gbé ìbéèrè méjì míì yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́: Ẹ̀kọ́ wo làwọn Júù ayé Ìsíkíẹ́lì rí kọ́ nípa ìlànà tí Jèhófà fi lélẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́ nínú ìran tí wòlíì náà rí? Ìdáhùn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká lè dáhùn ìbéèrè kejì, ìyẹn: Kí làwa tá à ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn lílekoko yìí rí kọ́ nínú ìran náà?

Ẹ̀kọ́ Wo Ni Ìran Náà Kọ́ Àwọn Èèyàn Nígbà Àtijọ́?

3. Kí nìdí tí ojú fi máa ti àwọn ọlọ́kàn títọ́ bí wọ́n ṣe mọ̀ pé ilé Jèhófà wà lórí òkè tó ga fíofío?

3 Ká lè dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká wo nǹkan mélòó kan nípa tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Òkè tó ga fíofío. Ó ṣeé ṣe kíyẹn rán àwọn èèyàn náà létí àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ pé wọ́n máa pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn. (Àìsá. 2:2) Ní báyìí tí wọ́n rí ilé Jèhófà lórí òkè tó ga fíofío, kí nìyẹn kọ́ wọn? Wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ pé ṣe ló yẹ káwọn gbé ìjọsìn mímọ́ ga ju ohunkóhun míì lọ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé kò dìgbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé ìjọsìn náà ga kó tó di gíga, torí pé Jèhófà tó ṣètò náà “ga fíìfíì ju gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù.” (Sm. 97:9) Àmọ́, àwọn èèyàn náà ni kò ṣe ohun tó tọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún ni wọ́n ti jẹ́ kí ìjọsìn mímọ́ di ẹlẹ́gbin, wọ́n sọ ọ́ dìdàkudà, wọ́n sì pa á tì. Bí wọ́n ṣe rí ibùjọsìn Ọlọ́run wọn tó wà lókè téńté, tí ògo rẹ̀ sì ń tàn yanran mú kí ojú ti àwọn ọlọ́kàn títọ́.

4, 5. Ẹ̀kọ́ wo làwọn èèyàn náà rí kọ́ látara àwọn ẹnubodè gíga tí tẹ́ńpìlì náà ni?

4 Àwọn ẹnubodè gíga. Ìbẹ̀rẹ̀ ni Ìsíkíẹ́lì ti rí i tí áńgẹ́lì náà ń wọn àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì náà. Ǹjẹ́ ẹ mọ bí àwọn ẹnubodè náà ṣe ga tó? Wọ́n ga tó ọgọ́rùn-ún (100) ẹsẹ̀ bàtà, ìyẹn nǹkan bí ilé alájà mẹ́wàá! (Ìsík. 40:14) Yàtọ̀ síyẹn, yàrá ẹ̀ṣọ́ wà láwọn ẹnubodè náà. Kí ni gbogbo èyí máa gbìn sọ́kàn àwọn tó ṣàyẹ̀wò àwòrán tẹ́ńpìlì náà? Jèhófà sọ fún Ìsíkíẹ́lì pé: “Fiyè sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà dáadáa.” Kí nìdí? Ìdí ni pé àwọn èèyàn náà ń mú àwọn tí “kò kọlà ọkàn àti ara” wá sínú ilé mímọ́ Jèhófà. Kí nìyẹn wá yọrí sí? Jèhófà sọ pé: “Wọ́n ń sọ tẹ́ńpìlì mi di aláìmọ́.”​—Ìsík. 44:​5, 7.

5 Ńṣe làwọn tí ‘kò kọlà ara’ rú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn èèyàn rẹ̀ látọjọ́ Ábúráhámù. (Jẹ́n. 17:​9, 10; Léf. 12:​1-3) Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù ni tàwọn tí “kò kọlà ọkàn.” Yàtọ̀ sí pé wọn kì í tẹ̀ lé òfin àti ìlànà Jèhófà, wọ́n tún jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀. Ẹ gbọ́ ná, ṣé ó yẹ kí wọ́n jẹ́ kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tiẹ̀ sún mọ́ ilé Jèhófà rárá, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé wọ́n ń wọnú rẹ̀? Jèhófà kórìíra àgàbàgebè, ìwà burúkú yìí gan-an làwọn èèyàn rẹ̀ sì fi ń ṣayọ̀ nínú ilé rẹ̀. Àwọn ẹnubodè àtàwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ tó wà nínú tẹ́ńpìlì inú ìran yẹn kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere, ìyẹn ni pé: Kò sáyè mọ́ fún ìwàkiwà! Ẹnikẹ́ni tó bá máa wá sínú ilé Jèhófà gbọ́dọ̀ kúnjú ìwọ̀n ìlànà gíga rẹ̀. Ìyẹn ló sì lè mú kí Jèhófà tẹ́wọ́ gba ìjọsìn àwọn èèyàn náà.

6, 7. (a) Kí ni Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn náà bó ṣe fí ọgbà tó tóbi gan-an yí tẹ́ńpìlì náà ká? (b) Irú ọwọ́ wo làwọn èèyàn náà fi mú ilé Jèhófà tẹ́lẹ̀? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

6 Ògiri tó yí i ká. Ohun míì tó tún yani lẹ́nu nípa tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ni ògiri tí wọ́n kọ́ yí tẹ́ńpìlì náà ká. Ìsíkíẹ́lì ròyìn pé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọ̀pá esùsú ni ògiri náà lẹ́gbẹ̀ẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, ìyẹn ẹgbẹ̀rún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún kan (5,100) ẹsẹ̀ bàtà. Àbẹ́ ò rí nǹkan! Ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan ògiri yẹn fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó máìlì kan. (Ìsík. 42:​15-20) Síbẹ̀, tẹ́ńpìlì yẹn fúnra rẹ̀ àti àgbàlá rẹ̀ kò ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ìgbọ̀nwọ́ tàbí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ààbọ̀ (850) ẹsẹ̀ bàtà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan. Torí náà, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn kọ́ ilé kékeré kan sí àárín ọgbà tó tóbi gan-an. a Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

7 Jèhófà sọ pé: “Kí wọ́n gbé àgbèrè ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe àti òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, èmi yóò sì máa gbé láàárín wọn títí láé.” (Ìsík. 43:9) Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn náà, “òkú àwọn ọba wọn” tọ́ka sí ìbọ̀rìṣà. Pẹ̀lú bí ọgbà tẹ́ńpìlì inú ìran náà ṣe tóbi gan-an, ṣe ló dà bí ìgbà tí Jèhófà ń sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ mú àwọn nǹkan ẹlẹ́gbin yìí jìnnà sí mi. Ẹ má ṣe jẹ́ kó sún mọ́ tòsí mi rárá.” Torí náà, tí wọ́n bá jẹ́ ki ìjọsìn wọn wà ní mímọ́, Jèhófà máa wà láàárín wọn.

8, 9. Kí làwọn èèyàn máa rí kọ́ látinú ìbáwí tó lágbára tí Jèhófà fún àwọn tó ń múpò iwájú?

8 Ìbáwí tó lágbára fáwọn tó ń múpò iwájú. Jèhófà fún àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìbáwí tó lágbára, àmọ́ ó ṣe bẹ́ẹ̀ tìfẹ́tìfẹ́. Bí àpẹẹrẹ, kò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nígbà tó ń bá àwọn ọmọ Léfì wí torí pé wọ́n pa ojúṣe wọn tì nígbà táwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í bọ̀rìṣà. Àmọ́ ó gbóríyìn fáwọn ọmọ Sádókù torí pé wọ́n ‘bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ibi mímọ́ Jèhófà nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi í sílẹ̀.’ Ó ṣe kedere pé ìwà kálukú wọn ló fi dá wọn lẹ́jọ́, ó sì fi àánú hàn sí wọn. (Ìsík. 44:​10, 12-16) Bákan náà, Jèhófà bá àwọn ìjòyè àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí gan-an torí ìwà burúkú wọn.​—Ìsík. 45:9.

9 Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ṣe kedere pé àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn èèyàn òun máa jíhìn lórí irú ọwọ́ tí wọ́n bá fi mú ojúṣe wọn. Kò sẹ́nì kankan nínú wọn tó kọjá ìmọ̀ràn àti ìbáwí Jèhófà. Torí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ rí i dájú pé àwọn ń fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ nínú bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà!

10, 11. Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ìgbèkùn tó pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn fi ẹ̀kọ́ inú ìran Ìsíkíẹ́lì sílò?

10 Ǹjẹ́ àwọn tó kúrò nígbèkùn yẹn fi àwọn ẹ̀kọ́ inú ìran Ìsíkíẹ́lì sílò? Ká sòótọ́, a ò lè mọ gbogbo bí ìran yẹn ṣe rí lára àwọn èèyàn náà tàbí ohun tí wọ́n rò nípa rẹ̀. Àmọ́, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn àti ọwọ́ tí wọ́n fi mú ìjọsìn mímọ́ Jèhófà. Ṣé wọ́n fi àwọn ìlànà inú ìran yẹn sílò? Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ dé àyè kan, pàápàá tá a bá fi wé ìwà àìṣòótọ́ táwọn baba ńlá wọn hù kí wọ́n tó lọ sígbèkùn Bábílónì.

11 Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ tó wà láàárín wọn rí i dájú pé àwọn èèyàn náà lóye ìlànà Jèhófà, bí irú èyí tó wà nínú ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí. Lára àwọn ọkùnrin olóòótọ́ yìí ni wòlíì Hágáì àti Sekaráyà, Ẹ́sírà àlùfáà tó tún jẹ́ akọ̀wé àti Nehemáyà tó jẹ́ gómìnà. (Ẹ́sírà 5:​1, 2) Wọ́n kọ́ àwọn èèyàn náà pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbé ìjọsìn mímọ́ ga, òun ló sì gbọ́dọ̀ gbawájú láyé wọn dípò àwọn ohun ìní tara. (Hág. 1:​3, 4) Wọ́n rí i dájú pé ẹni bá máa lọ́wọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìlànà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Ẹ́sírà àti Nehemáyà fún àwọn kan ní ìbáwí tó lágbára torí pé wọ́n fẹ́ àwọn àjèjì, ìyẹn àwọn obìnrin tí kò jẹ́ kí wọ́n sin Jèhófà bó ṣe yẹ. (Ka Ẹ́sírà 10:​10, 11; Neh. 13:​23-27, 30) Kí làwọn èèyàn náà ṣe nípa ìbọ̀rìṣà? Ó jọ pé lẹ́yìn tí wọ́n pa dà sílùú ìbílẹ̀ wọn, wọn ò fàyè gba ohunkóhun tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà rárá àti rárá, ó ṣe tán ọ̀pọ̀ ìgbà ni ẹ̀ṣẹ̀ burúkú yìí ti mú kí orílẹ̀-èdè náà pàdánù ojúure Jèhófà. Ṣé àwọn àlùfáà àtàwọn ìjòyè náà fi ohun tí wọ́n kọ́ sílò? Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, Jèhófà fún àwọn náà ní ìbáwí tó lágbára. (Neh. 13:​22, 28) Ọ̀pọ̀ lára wọn ló fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí Jèhófà, wọ́n sì fi ìmọ̀ràn rẹ̀ sílò.​—Ẹ́sírà 10:​7-9, 12-14; Neh. 9:​1-3, 38.

Bí Nehemáyà àtàwọn èèyàn náà ṣe jọ ń ṣiṣẹ́, ó ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìjọsìn mímọ́ (Wo ìpínrọ̀ 11)

12. Báwo ni Jèhófà ṣe bù kún àwọn tó pa dà dé láti ìgbèkùn?

12 Inú Jèhófà dùn sáwọn èèyàn náà, ó sì bù kún wọn. Wọ́n gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ní ìlera tó dáa, ìlú wọn sì tòrò minimini, ó yàtọ̀ sí bó ṣe wà tipẹ́tipẹ́. (Ẹ́sírà 6:​19-22; Neh. 8:​9-12; 12:​27-30, 43) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn èèyàn náà bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé àwọn ìlànà òdodo Jèhófà nípa ìjọsìn mímọ́. Kò sí àní-àní pé èyí tó pọ̀ jù lára wọn ló fi àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìran náà sọ́kàn. Tá a bá ṣàkópọ̀ ẹ̀kọ́ táwọn èèyàn náà kọ́ nínú ìran Ìsíkíẹ́lì, a lè pín in sọ́nà méjì. (1) Ó jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ìlànà Jèhófà tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn mímọ́, wọ́n sì kọ́ bí wọ́n ṣe lè fi àwọn ìlànà náà sílò. (2) Ó tún fi àwọn èèyàn náà lọ́kàn balẹ̀. Ó mú kó dá wọn lójú pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò àti pé Jèhófà máa bù kún wọn tí wọ́n bá fi ìjọsìn rẹ̀ sípò tó yẹ. Àmọ́ o, ìbéèrè kan wà tó yẹ ká dáhùn: Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ lóde òní?

Ohun Tí Ìran Ìsíkíẹ́lì Kọ́ Wa Lónìí

13, 14. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí kàn wá lónìí? (b) Ẹ̀kọ́ méjì wo ni ìran náà kọ́ wa lónìí? (Tún wo àpótí 13A, “Tẹ́ńpìlì Méjì Tó Yàtọ̀ Síra àti Ohun Tó Kọ́ Wa.”)

13 Ṣé ó dá wa lójú pé ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí kàn wá lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni! Ẹ rántí pé orí “òkè kan tó ga fíofío” ni tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí wà, ìyẹn sì jọra pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tí Àìsáyà sọ pé “òkè ilé Jèhófà” máa “fìdí múlẹ̀ gbọn-in sórí àwọn òkè.” Àìsáyà dìídì sọ pé àsọtẹ́lẹ̀ náà máa ṣẹ “ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” tàbí “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Ìsík. 40:2; Àìsá. 2:​2-4; àlàyé ìsàlẹ̀; tún wo Míkà 4:​1-4.) Àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wa yìí làwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń tọ́ka sí, pàápàá látọdún 1919 nígbà tá a mú ìjọsìn mímọ́ pa dà bọ̀ sípò, tá a sì gbé e ga, tó fi dà bíi pé a gbé e sórí òkè tó ga fíofío. b

14 Ó ṣe kedere nígbà náà pé ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí kan ìjọsìn mímọ́ lónìí. Bíi tàwọn Júù tó ti ìgbèkùn dé, àwa náà lè ṣàkópọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tá a kọ́ nínú ìran náà sọ́nà méjì. (1) Ó jẹ́ ká mọ àwọn ìlànà Jèhófà tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn mímọ́ àti bá a ṣe lè fi wọ́n sílò. (2) Ó tún fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò àti pé Jèhófà máa bù kún àwa èèyàn rẹ̀.

Àwọn Ìlànà Tó Wà fún Ìjọsìn Mímọ́ Lóde Òní

15. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn bá a ṣe ń ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí?

15 Ẹ jẹ́ ká gbé apá mélòó kan yẹ̀ wò nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí. Jẹ́ ká sọ pé a jọ wà pẹ̀lú Ìsíkíẹ́lì bí wọ́n ṣe ń mú un yí ká tẹ́ńpìlì náà. Má gbàgbé pé kì í ṣe tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí là ń rí; kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn Jèhófà la fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Kí wá làwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ nínú ìran náà lónìí?

16. Kí la rí kọ́ nínú gbogbo ohun tí áńgẹ́lì náà wọ̀n nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ orí yìí.)

16 Kí nìdí tó fi wọn tẹ́ńpìlì yẹn? Nínú ìran yẹn, Ìsíkíẹ́lì ń wo bí áńgẹ́lì tó ní ìrísí bàbà yẹn ṣe ń wọn tẹ́ńpìlì náà tinú-tòde, tó wọn àwọn ògiri rẹ̀, ẹnubodè, àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́, àgbàlá tẹ́ńpìlì náà àti pẹpẹ. Bó ṣe ń ti orí ọ̀kan bọ́ sí òmíì lè fẹ́ kani láyà. (Ìsík. 40:1–42:20; 43:​13, 14) Kí wá la lè rí kọ́ nínú bí áńgẹ́lì yẹn ṣe wọn ilé náà àtàwọn nǹkan míì? Jèhófà fẹ́ ká mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà òun. Òun ló fàwọn ìlànà yẹn lélẹ̀, kì í ṣe ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí. Torí náà, àṣìṣe gbáà ló máa jẹ́ tẹ́nì kan bá sọ pé kò sí béèyàn ṣe jọ́sìn Ọlọ́run tí kò ní tẹ́wọ́ gbà á. Yàtọ̀ síyẹn, bí áńgẹ́lì yẹn ṣe fara balẹ̀ wọn tẹ́ńpìlì náà tinú-tòde mú kó dá wa lójú pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò láìsí-tàbí-ṣùgbọ́n. Bí wọ́n ṣe wọn tẹ́ńpìlì náà lọ́nà tó pé pérépéré, bẹ́ẹ̀ làwọn ìlérí Jèhófà náà ṣe máa ṣẹ láìkù síbì kan. Nípa bẹ́ẹ̀, Ìsíkíẹ́lì mú kó dá wa lójú pé ìjọsìn mímọ́ máa pa dà bọ̀ sípò láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí!

Kí la rí kọ́ látinú bí wọ́n ṣe wọn tinú-tòde tẹ́ńpìlì náà? (Wo ìpínrọ̀ 16)

17. Kí ni ògiri tó yí tẹ́ńpìlì náà ká rán wa létí rẹ̀ lóde òní?

17 Ògiri tó yí i ká. Bá a ṣe sọ ṣáájú, Ìsíkíẹ́lì rí ògiri tó yí tẹ́ńpìlì náà ká nínú ìran. Ìyẹn tẹ̀ ẹ́ mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́kàn pé wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwà àìmọ́ èyíkéyìí látinú ìjọsìn èké wọnú ìjọsìn mímọ́ rárá, wọn ò gbọ́dọ̀ kó àbààwọ́n bá ilé Ọlọ́run. (Ka Ìsíkíẹ́lì 43:​7-9.) Ẹ ò rí i pé ìmọ̀ràn yẹn kàn wá gbọ̀ngbọ̀n lóde òní! Lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ sílẹ̀ kúrò nígbèkùn tẹ̀mí tí wọ́n ti wà fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Bábílónì Ńlá, Kristi yan ẹrú olóòótọ́ àti olóye lọ́dún 1919. Látìgbà yẹn, àwa èèyàn Ọlọ́run ń sa gbogbo ipá wa láti jáwọ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tó jẹ mọ́ ìbọ̀rìṣà àti ẹ̀sìn àwọn kèfèrí. À ń rí i dájú pé a ò jẹ́ kí ìwà àìmọ́ èyíkéyìí nípa tẹ̀mí wọnú ìjọsìn mímọ́ rárá. Bákan náà, a kì í bójú tó ọ̀rọ̀ ìṣòwò ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, a kì í jẹ́ kí irú àwọn nǹkan tara bẹ́ẹ̀ wọnú ìjọsìn wa rárá.​—Máàkù 11:​15, 16.

18, 19. (a) Kí la rí kọ́ nínú bí àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì náà ṣe ga? (b) Kí ló yẹ ká ṣe tí àwọn kan bá fẹ́ bomi la àwọn ìlànà gíga Jèhófà? Sọ àpẹẹrẹ kan.

18 Àwọn ẹnubodè gíga. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ tá a bá ronú nípa àwọn ẹnubodè gíga tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran? Ó dájú pé àwọn ẹnubodè yẹn kọ́ àwọn Júù tó wà nígbèkùn lẹ́kọ̀ọ́ pé ìlànà gíga ni Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ máa tẹ̀ lé tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ kí wọ́n hùwà. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà àtijọ́, òde òní wá ńkọ́? Inú tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí la ti ń jọ́sìn Jèhófà báyìí. Ẹ ò rí i pé àsìkò yìí gan-an ló yẹ ká túbọ̀ máa hùwà mímọ́ láìsí ẹ̀tàn èyíkéyìí. (Róòmù 12:9; 1 Pét. 1:​14, 15) Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, Jèhófà ò yéé kọ́ àwa èèyàn rẹ̀ ká lè máa hùwà rere tó bá ìlànà rẹ̀ mu. c Bí àpẹẹrẹ, a máa ń yọ àwọn oníwà àìtọ́ tí kò ronú pìwà dà lẹ́gbẹ́ nínú ìjọ. (1 Kọ́r. 5:​11-13) Yàtọ̀ síyẹn, àwọn yàrá ẹ̀ṣọ́ tó wà láwọn ibi àbáwọlé àwọn ẹnubodè yẹn tún lè rán wa létí pé, tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn Jèhófà lóde òní, ẹni tí Jèhófà ò bá tẹ́wọ́ gbà ò lè wọlé sọ́dọ̀ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ẹni tó pera ẹ̀ ní Kristẹni, àmọ́ tó ń hùwà tí kò tọ́ lábẹ́lẹ̀ lè wá sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, àmọ́ kò lè rí ojúure Jèhófà àfi tó bá ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. (Jém. 4:8) Ẹ ò rí i pé ààbò gidi nìyẹn jẹ́ fún ìjọsìn mímọ́ lásìkò tí ìwà ìbàjẹ́ gbòde kan yìí!

19 Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé, kí òpin tó dé, ìwà ìbàjẹ́ máa pọ̀ gan-an láyé. Ó ní: “Àwọn èèyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà á máa burú sí i, wọ́n á máa ṣi àwọn èèyàn lọ́nà, wọ́n á sì máa ṣi àwọn náà lọ́nà.” (2 Tím. 3:13) Wọ́n ń ṣi àwọn èèyàn púpọ̀ sí i lọ́nà lóde òní, wọ́n sì ń mú kí wọ́n máa ronú pé àwọn ìlànà gíga Jèhófà ti le koko jù, pé kò bóde mu mọ́ tàbí pé kò tiẹ̀ dáa rárá. Ṣé wàá jẹ́ kí wọ́n tàn ẹ́ jẹ? Bí àpẹẹrẹ, tẹ́nì kan bá fẹ́ kó o gbà pé ìlànà Ọlọ́run ò tọ̀nà lórí ọ̀rọ̀ kí ọkùnrin máa bá ọkùnrin lò pọ̀ tàbí kí obìnrin máa bá obìnrin lò pọ̀, ṣé wàá gbà pẹ̀lú onítọ̀hún? Àbí wàá fara mọ ohun tí Jèhófà sọ ní kedere nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn tó ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ “ń ṣe ohun ìbàjẹ́”? Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa pé a ò gbọ́dọ̀ ṣètìlẹ́yìn fún ìwà ìṣekúṣe. (Róòmù 1:​24-27, 32) Tọ́rọ̀ tó jẹ mọ́ irú ìwàkiwà bẹ́ẹ̀ bá délẹ̀, ó máa dáa ká ronú nípa bí tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran ṣe ní àwọn ẹnubodè tó ga, ká sì rántí pé: Jèhófà kì í rẹ àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ gíga wálẹ̀, láìka ohun táráyé ń sọ pé àwọn fẹ́ sí. Ṣé àwa náà fara mọ́ Baba wa ọ̀run, tá a sì ń gbé ohun tó tọ́ lárugẹ?

À ń rú “ẹbọ ìyìn” nígbà tá a bá kópa nínú ìjọsìn mímọ́

20. Àwọn ìránnilétí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ wo ni àwọn “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” lè rí gbà nínú ìran Ìsíkíẹ́lì?

20 Àgbàlá tẹ́ńpìlì náà. Nígbà tí Ìsíkíẹ́lì rí bí àgbàlá ìta tẹ́ńpìlì náà ṣe fẹ̀ tó, ó ṣeé ṣe kínú rẹ̀ dùn gan-an bó ṣe ń ronú nípa bí àwọn tó máa kóra jọ sínú àgbàlá náà láti fayọ̀ sin Jèhófà ṣe máa pọ̀ tó. Lóde òní, ibi tó tún jẹ́ mímọ́ jùyẹn lọ fíìfíì làwa Kristẹni ti ń jọ́sìn Jèhófà. Ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí fún àwọn tó wà lára “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” tí wọ́n ń jọ́sìn Jèhófà ní àgbàlá ìta tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ní àwọn ìránnilétí kan tó gbé wọn ró. (Ìfi. 7:​9, 10, 14, 15) Ìsíkíẹ́lì kíyè sí i pé àwọn yàrá ìjẹun wà yí ká àgbàlá náà níbi tí àwọn tó wá jọ́sìn ti lè jẹ lára àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tí wọ́n mú wá. (Ìsík. 40:17) Ṣe ló dà bí ìgbà tí àwọn àti Jèhófà jọ ń jẹun, ìyẹn sì jẹ́ àmì pé wọ́n wà lálàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run! Lóde òní, a kì í fi ẹran rúbọ bíi tàwọn Júù tí wọ́n ń tẹ̀ lé Òfin Mósè. Kàkà bẹ́ẹ̀, à ń rú “ẹbọ ìyìn” nígbà tá a bá kópa nínú ìjọsìn mímọ́, irú bí ìgbà tá a bá dáhùn tàbí tá a sọ ohun tá a gbà gbọ́ láwọn ìpàdé wa tàbí lóde ẹ̀rí. (Héb. 13:15) Bákan náà, à ń gbádùn àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa. Abájọ tó fi máa ń ṣe wá bíi tàwọn ọmọ Kórà tí wọ́n kọrin sí Jèhófà pé: “Ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbikíbi!”​—Sm. 84:10.

21. Kí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lè rí kọ́ lára àwọn àlùfáà inú ìran Ìsíkíẹ́lì?

21 Àwọn àlùfáà. Ìsíkíẹ́lì kíyè sí i pé irú ẹnubodè táwọn tí kì í ṣe ara ìdílé àlùfáà ń gbà wọ àgbàlá ìta náà ni àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì ń gbà wọ àgbàlá inú. Ìyẹn rán àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àlùfáà létí pé àwọn náà gbọ́dọ̀ dójú ìlà àwọn ohun tí Jèhófà béèrè fún ìjọsìn mímọ́. Òde òní wá ńkọ́? Kò sí ètò ìdílé àlùfáà láàárín àwa èèyàn Ọlọ́run lóde òní, àmọ́ a sọ fún àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró pé: “Ẹ̀yin jẹ́ ‘ẹ̀yà àyànfẹ́, ẹgbẹ́ àlùfáà aládé.’ ” (1 Pét. 2:9) Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, àgbàlá tí àwọn àlùfáà ti ń jọ́sìn yàtọ̀ sí tàwọn èèyàn yòókù. Lóde òní, ibi tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ń jọ́sìn ò yàtọ̀ sí tàwọn yòókù tí wọ́n jọ ń sin Jèhófà lọ́nà èyíkéyìí tá a lè fojú rí, àmọ́ wọ́n ń gbádùn àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Jèhófà torí ó ti sọ wọ́n dọmọ. (Gál. 4:​4-6) Síbẹ̀, ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí yìí lè rán àwọn ẹni àmì òróró létí nǹkan mélòó kan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn náà rí i pé ìmọ̀ràn àti ìbáwí ò yọ àwọn àlùfáà sílẹ̀. Ó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni máa rántí pé “agbo kan” ni gbogbo wa lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan.”​—Ka Jòhánù 10:16.

22, 23. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn Kristẹni alàgbà lóde òní lè rí kọ́ lára ìjòyè tí Ìsíkíẹ́lì mẹ́nu bà nínú ìran? (b) Kí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?

22 Ìjòyè. Nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí, ẹni tó jẹ́ ìjòyè náà wà nípò àṣẹ dé àyè kan. Ìjòyè náà ò wá láti ìdílé àlùfáà, bí wọ́n sì ṣe ṣètò iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abẹ́ àbójútó àwọn àlùfáà ló ti ń ṣiṣẹ́. Àmọ́, ó ṣe kedere pé iṣẹ́ àbójútó ló ń ṣe fún àwọn èèyàn náà, ó sì ń bá wọn mú ẹbọ wá. (Ìsík. 44:​2, 3; 45:​16, 17; 46:2) Torí náà, ó jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kristẹni lóde òní tí wọ́n ní àwọn ojúṣe kan nínú ìjọ. Ó ṣe tán, àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ alàgbà, títí kan àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ìdarí ẹrú olóòótọ́ tí Ọlọ́run yàn. (Héb. 13:17) Àwọn alàgbà máa ń ṣiṣẹ́ kára láti ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́ kí wọ́n lè rú ẹbọ ìyìn láwọn ìpàdé Kristẹni àti lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. (Éfé. 4:​11, 12) Ó tún yẹ káwọn alàgbà kíyè sí bí Jèhófà ṣe bá àwọn ìjòyè Ísírẹ́lì wí, torí wọ́n lo agbára wọn nílòkulò. (Ìsík. 45:9) Bíi tàwọn ìjòyè yẹn, kò yẹ káwọn alàgbà rò pé àwọn ti kọjá ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń mọyì àǹfààní èyíkéyìí tí wọ́n bá ní láti gba ìtọ́sọ́nà Jèhófà kí wọ́n lè túbọ̀ sunwọ̀n sí i lẹ́nu iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn àti alábòójútó.​—Ka 1 Pétérù 5:​1-3.

23 Títí ayé fi máa di Párádísè, Jèhófà ò ní yéé fún wa láwọn alàgbà tó dáńgájíà, tí wọ́n sì jẹ́ alábòójútó onífẹ̀ẹ́. Lọ́rọ̀ kan, a lè sọ pé ṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà wa lónìí ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n lè jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó kúnjú ìwọ̀n tó sì máa wúlò nínú Párádísè. (Sm. 45:16) Ẹ ò rí i bínú wa ṣe máa ń dùn tó tá a bá ronú nípa bá a ṣe máa jàǹfààní látara àwọn ọkùnrin yìí nínú ayé tuntun! Bíi tàwọn àsọtẹ́lẹ̀ yòókù tó dá lórí bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò, tí àsìkò bá ṣe ń tó lójú Jèhófà la óò túbọ̀ máa ní òye tó kún rẹ́rẹ́ nípa àwọn ohun tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ọjọ́ iwájú làwọn apá kan nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà á wá ṣẹ lọ́nà tó kàmàmà, kò dájú pé òye wa lè gbé gbogbo ìyẹn báyìí. Àfi ká ní sùúrù dìgbà yẹn.

Kí ni àwọn ẹnubodè tó ga àtàwọn àgbàlá náà kọ́ wa nípa ìjọsìn wa? (Wo ìpínrọ̀ 18 sí 21)

Jèhófà Bù Kún Ìjọsìn Mímọ́

24, 25. Báwo ni ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí ṣe jẹ́ ká mọ bí Jèhófà ṣe máa bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọn ò bá jáwọ́ nínú ìjọsìn mímọ́?

24 Paríparí ẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé ohun pàtàkì kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìran tí Ìsíkíẹ́lì rí. Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì inú ìran yẹn, ó sì ṣèlérí fáwọn èèyàn rẹ̀ pé òun á wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn tí wọ́n bá ń rí i dájú pé àwọn ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà tí òun fi lélẹ̀ fún ìjọsìn mímọ́. (Ìsík. 43:​4-9) Bí Jèhófà ṣe wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn, ipa wo ni èyí máa ní lórí àwọn èèyàn náà àti ilẹ̀ wọn?

25 Àwòrán ohun méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìran náà fi sàsọtẹ́lẹ̀ tó fi dá àwọn èèyàn náà lójú pé wọ́n á rí ìbùkún Ọlọ́run: (1) Odò kan ṣàn jáde láti ibi mímọ́ tẹ́ńpìlì, ó sọ ilẹ̀ náà di alààyè, ó sì mú kó méso jáde; àti pé (2) wọ́n pín ilẹ̀ náà létòlétò, ní ìwọ̀n tó yẹ, tẹ́ńpìlì náà àti ilẹ̀ tó yí i ká sì wà ní àárín gbùngbùn. Báwo ló ṣe yẹ ká lóye ọ̀rọ̀ yẹn lóde òní? Ó ṣe tán, lákòókò tá à ń gbé yìí, Jèhófà ti wọlé wá, ó ti yọ́ wa mọ́, ó sì ti fọwọ́ sí ọ̀nà ìjọsìn tó jẹ́ mímọ́ ju tìgbà yẹn lọ, ìyẹn tẹ́ńpìlì ńlá tẹ̀mí. (Mál. 3:​1-4) A máa jíròrò asọtẹ́lẹ̀ méjèèjì yẹn ní Orí 19 sí 21 nínú ìwé yìí.

a Jèhófà ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ fáwọn èèyàn náà pé òun ò ní jẹ́ kí wọ́n sọ ilé mímọ́ òun dìdàkudà bíi ti tẹ́lẹ̀, ó sọ pé: “Wọ́n fi ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin bí wọ́n ṣe gbé ibi àbáwọlé wọn sí ẹ̀gbẹ́ ibi àbáwọlé mi, tí wọ́n sì gbé férémù ẹnu ọ̀nà wọn sí ẹ̀gbẹ́ férémù ẹnu ọ̀nà mi, ògiri nìkan ló sì wà láàárín èmi àti àwọn.” (Ìsík. 43:8) Nílùú Jerúsálẹ́mù àtijọ́, ṣe làwọn èèyàn kọ́lé gbe tẹ́ńpìlì náà, ọpẹ́lọpẹ́ ògiri tó yí i ká. Torí náà, bí wọ́n ṣe pa ìlànà òdodo Jèhófà tì, ṣe ni wọ́n mú ìwà ẹ̀gbin àti ìbọ̀rìṣà wọn sún mọ́ tòsí ilé Jèhófà. Kò sí àní-àní pé ohun ìríra gbáà nìyẹn!

b Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí tún bá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ míì tó nímùúṣẹ lọ́jọ́ ìkẹyìn mu nípa bí nǹkan ṣe pa dà bọ̀ sípò. Bí àpẹẹrẹ, wo bí Ìsíkíẹ́lì 43:​1-9 àti Málákì 3:​1-5 ṣe jọra; bákan náà, wo bí Ìsíkíẹ́lì 47:​1-12 àti Jóẹ́lì 3:18 ṣe jọra.

c Ọdún 29 Sànmánì Kristẹni ni tẹ́ńpìlì tẹ̀mí kọ́kọ́ wá sójú táyé, nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi tó sì di Àlùfáà Àgbà. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn èèyàn fi pa ìjọsìn mímọ́ tì lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì kú. Àmọ́ látọdún 1919, ní pàtàkì, la ti gbé ìjọsìn mímọ́ ga.