Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 1B

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

Lápapọ̀, a lè pín ìwé Ìsíkíẹ́lì bá a ṣe tò ó yìí:

ORÍ 1 SÍ 3

Lọ́dún 613 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Ìsíkíẹ́lì ń gbé láàárín àwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì, ó rí ìran látọ̀dọ̀ Jèhófà, Jèhófà sì rán an níṣẹ́ pé kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù tí wọ́n ń gbé lẹ́bàá odò Kébárì.

ORÍ 4 SÍ 24

Láti ọdún 613 sí 609 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Ìsíkíẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìdájọ́ tó máa dé sórí Jerúsálẹ́mù àtàwọn èèyàn ibẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ àti abọ̀rìṣà.

ORÍ 25 SÍ 32

Bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 609 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọdún tí àwọn ará Bábílónì pa dà wá dó ti Jerúsálẹ́mù, àsọtẹ́lẹ̀ ìdájọ́ tí Ìsíkíẹ́lì ń sọ yí pa dà kúrò lórí Jerúsálẹ́mù sórí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá, ìyẹn Ámónì, Édómù, Íjíbítì, Móábù, Filísíà, Sídónì àti Tírè.

ORÍ 33 SÍ 48

Bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 606 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ ṣì wà ní àwókù níbi tó jìnnà réré, Ìsíkíẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọtẹ́lẹ̀ bí nǹkan ṣe máa dáa, ó sọ ohun tó wúni lórí gan-an nípa bí ìjọsìn mímọ́ Jèhófà Ọlọ́run ṣe máa pa dà bọ̀ sípò.

Bí wọ́n ṣe to àwọn ohun tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì bá bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe tẹ̀ léra mu, ó sì tún bá ohun tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà dá lé mu. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ ló ṣáájú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. Ìyẹn bọ́gbọ́n mu, torí pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò fi hàn pé àsìkò kan wà tí ẹnikẹ́ni ò ṣe ìjọsìn ní tẹ́ńpìlì.

Yàtọ̀ síyẹn, àkọsílẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ìsíkíẹ́lì sọ lòdì sí orílẹ̀-èdè àwọn ọ̀tá tó yí wọn ká (orí 25 sí 32) wà láàárín ìkéde ìdájọ́ tó ṣe sórí Jerúsálẹ́mù àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọsìn mímọ́ ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìkéde ìdájọ́ tí Ìsíkíẹ́lì sọ lòdì sí àwọn orílẹ̀-èdè, ó ní: “Ó bá a mu gan-an bí àwọn ìkéde náà ṣe wà láàárín àwọn ọ̀rọ̀ ìbínú Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe fi àánú hàn sí àwọn èèyàn Rẹ̀, torí pé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ fìyà jẹ àwọn ọ̀tá yẹn wà lára ọ̀nà tó gbà dá àwọn èèyàn Rẹ̀ nídè.”

Pa dà sí orí 1, ìpínrọ̀ 18