Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 10D

Ó Ń Mú Ká Pa Dà Dìde Dúró

Ó Ń Mú Ká Pa Dà Dìde Dúró

ÌGBÀGBỌ́ wa túbọ̀ máa lágbára tá a bá ń ronú lórí ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ látinú àwọn ìran amóríyá tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì 37:1-14. Ẹ̀kọ́ náà máa wúlò fún wa láìka ẹni tá a jẹ́ sí. Ẹ̀kọ́ wo nìyẹn?

Nígbà míì, ìṣòro ìgbésí ayé lè mu wá lómi gan-an, kó mú kí gbogbo nǹkan sú wa, kó sì máa tán wa lókun. Àmọ́ tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a lè rí okun gbà tá a bá ronú lórí ìran tó ṣe kedere tí Ìsíkíẹ́lì rí nípa bí nǹkan ṣe máa pa dà bọ̀ sípò. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Àsọtẹ́lẹ̀ yìí fi dá wa lójú pé Ọlọ́run tó lágbára láti fi èémí sínú egungun gbígbẹ tó sì mú kó di alààyè lè fún wa lókun tá a nílò láti borí òkè ìṣòro èyíkéyìí, títí kan àwọn ìṣòro tó ju agbára àwa èèyàn lọ.​—Ka Sáàmù 18:29; Fílí. 4:13.

Ká má gbàgbé pé ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà ayé Ìsíkíẹ́lì, Mósè, tí òun náà jẹ́ wòlíì sọ pé Jèhófà lágbára, ó sì máa ń wù ú láti fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Mósè kọ̀wé pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ààbò láti ìgbà àtijọ́, ọwọ́ ayérayé rẹ̀ wà lábẹ́ rẹ.” (Diu. 33:27) Ó dá wa lójú pé, tá a bá yíjú sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa nígbà ìṣòro, Jèhófà máa fìfẹ́ gbé ọwọ́ lé wa, á rọra fi ọwọ́ rẹ̀ gbé wa, á sì mú ká pa dà dìde dúró.​—Ìsík. 37:10.