Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÀPÓTÍ Ẹ̀KỌ́ 13A

Tẹ́ńpìlì Méjì Tó Yàtọ̀ Síra àti Ohun Tó Kọ́ Wa

Tẹ́ńpìlì Méjì Tó Yàtọ̀ Síra àti Ohun Tó Kọ́ Wa

Ìran Tẹ́ńpìlì Tí Ìsíkíẹ́lì Rí:

  • Àwọn Júù tó wà nígbèkùn Bábílónì ni Ìsíkíẹ́lì sọ ọ́ fún

  • Ó ní pẹpẹ kan tí wọ́n ti ń rú onírúurú ẹbọ

  • Ó jẹ́ ká mọ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà nípa ìjọsìn mímọ́

  • Ó jẹ́ ká rí bí ìjọsìn mímọ́ ṣe pa dà bọ̀ sípò bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919

Tẹ́ńpìlì Ńlá Tẹ̀mí:

  • Àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù ni Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ẹ̀ fún

  • Ó ní pẹpẹ kan tí wọ́n ti rú ẹbọ kan “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé” (Héb. 10:10)

  • Ó jẹ́ ká mọ ohun gidi tí àgọ́ ìjọsìn àti tẹ́ńpìlì táwọn ọmọ Ísírẹ́lì lò ṣàpẹẹrẹ, ìyẹn ètò tí Jèhófà ṣe fún ìjọsìn mímọ́ lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi

  • Ó jẹ́ ká túbọ̀ rí iṣẹ́ tí Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà Tó Tóbi Jù ṣe látọdún 29 sí 33 Sànmánì Kristẹni.