Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 3

Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ

Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ

Mátíù 16:13-16

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Fi ọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, táá mú kí wọ́n máa fọkàn bá ẹ lọ, táá mú kí wọ́n ronú jinlẹ̀, táá sì gbé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ yọ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ kí wọ́n sì máa fọkàn bá ẹ lọ. Bi wọ́n ní ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ tàbí èyí táá jẹ́ kí wọ́n máa fojú sọ́nà fún ìdáhùn.

  • Mú kí wọ́n ronú lórí kókó ọ̀rọ̀ kan. Jẹ́ kí àwọn tí ò ń bá sọ̀rọ̀ rí i pé àlàyé rẹ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, o lè béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí wọ́n rí i pé ohun tí ò ń sọ bọ́gbọ́n mu lóòótọ́.

  • Jẹ́ kí àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ ṣe kedere. Tó o bá fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa kókó pàtàkì kan, kọ́kọ́ béèrè ìbéèrè kan tó gbàfíyèsí. Béèrè àwọn ìbéèrè kan lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ nípa kókó pàtàkì kan tàbí nígbà tó o bá fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ.