Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 12

Ọ̀yàyà àti Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò

Ọ̀yàyà àti Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò

1 Tẹsalóníkà 2:​7, 8

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Fi ìmọ̀lára tó yẹ sọ̀rọ̀, jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ wọn, o sì fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Ronú nípa àwọn tó o fẹ́ bá sọ̀rọ̀. Tó o bá ń múra ọ̀rọ̀ rẹ sílẹ̀, ronú nípa àwọn ìṣòro wọn àti bí àwọn ìṣòro yẹn ṣe rí lára wọn.

  • Fara balẹ̀ ronú nípa ohun tó o máa sọ. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ tura, kó tuni nínú, kó sì fúnni lókun. Má ṣe sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó máa bí wọn nínú, má sì ṣe sọ̀rọ̀ àbùkù nípa àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́.

  • Fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wọn. Tó o bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tó o sì ń fara ṣàpèjúwe bó ṣe yẹ, wàá fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọn ká ẹ lára. Má ṣe jẹ́ kí ojú rẹ le koko; máa rẹ́rìn-ín músẹ́.