Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 08

Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà

Bó O Ṣe Lè Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà

Jèhófà fẹ́ kó o túbọ̀ mọ òun. Kí nìdí? Ìdí ni pé bó o bá ṣe ń mọ ìwà àti ìṣe Jèhófà sí i, tí ò ń mọ bó ṣe ń ṣe nǹkan, àtohun tó fẹ́ ṣe fáwa èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa sún mọ́ ọn. Ṣé o gbà pé o lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? (Ka Sáàmù 25:14.) Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè yìí, ó sì tún sọ ìdí tó fi jẹ́ pé kéèyàn jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ.

1. Kí ni Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe?

“Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, á sì sún mọ́ yín.” (Jémíìsì 4:8) Kí ni ọ̀rọ̀ yẹn túmọ̀ sí? Jèhófà ń rọ̀ ẹ́ pé kó o di ọ̀rẹ́ òun. Àwọn kan gbà pé ó máa ṣòro gan-an láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run torí pé àwa èèyàn ò lè rí Ọlọ́run. Síbẹ̀, nínú Bíbélì, Jèhófà jẹ́ ká mọ gbogbo ohun tó yẹ ká mọ̀ nípa ìwà àti ìṣe òun ká lè sún mọ́ ọn. Tá a bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì, ọ̀rẹ́ àwa àti Jèhófà á máa jinlẹ̀ sí i, bá ò tiẹ̀ rí i.

2. Kí nìdí tí Jèhófà fi jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ?

Kò sẹ́ni tó lè nífẹ̀ẹ́ rẹ tó bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ó fẹ́ kó o máa láyọ̀, kó o sì máa gbàdúrà sí òun nígbàkigbà tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́. Torí náà, ‘máa kó gbogbo àníyàn rẹ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ torí ó ń bójú tó ẹ.’ (1 Pétérù 5:7) Jèhófà múra tán láti ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ó múra tán láti tù wọ́n nínú, ó sì máa ń tẹ́tí sí wọn.​—Ka Sáàmù 94:18, 19.

3. Kí ni Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe?

Jèhófà nífẹ̀ẹ́ gbogbo èèyàn, “ṣùgbọ́n àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Jèhófà fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa sapá láti tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀, kí wọ́n sì máa sá fún ìwà burúkú. Àwọn kan rò pé agbára àwọn ò lè gbé e láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Jèhófà. Àmọ́, Jèhófà máa ń gba tiwa rò. Ó máa ń tẹ́wọ́ gba gbogbo ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tó sì ń sapá láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.​—Sáàmù 147:11; Ìṣe 10:34, 35.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà, kó o sì mọ ìdí tó fi jẹ́ ọ̀rẹ́ tó dáa jù lọ.

4. Ọ̀rẹ́ Jèhófà ni Ábúráhámù

Ìtàn Ábúráhámù (tó tún ń jẹ́ Ábúrámù) nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ bí èèyàn ṣe lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Kà nípa Ábúráhámù ní Jẹ́nẹ́sísì 12:1-4. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni Jèhófà sọ pé kí Ábúráhámù ṣe?

  • Ìlérí wo ni Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù?

  • Kí ni Ábúráhámù ṣe nígbà tí Jèhófà tọ́ ọ sọ́nà?

5. Ohun tí Jèhófà fẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ òun máa ṣe

A sábà máa ń retí kí àwọn ọ̀rẹ́ wa ṣe àwọn ohun kan fún wa.

  • Àwọn nǹkan wo lo fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún ẹ?

Ka 1 Jòhánù 5:3, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni Jèhófà ń retí pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ máa ṣe?

Ká lè máa ṣègbọràn sí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ yí ìwà wa tàbí ìṣe wa pa dà. Ka Àìsáyà 48:17, 18, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe àwọn àyípadà kan?

Ohun tó máa dáàbò bò wá ni ọ̀rẹ́ gidi máa ń sọ pé ká ṣe, ó sì máa ń gbà wá nímọ̀ràn tó máa ṣe wá láǹfààní. Ohun kan náà ni Jèhófà máa ń ṣe fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀

6. Bí Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́

Jèhófà máa ń ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fara da àwọn ìṣòro. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Báwo ni Jèhófà ṣe ran obìnrin tó wà nínú fídíò yìí lọ́wọ́ kó lè borí èrò tí ò tọ́ àti ẹ̀dùn ọkàn?

Ka Àìsáyà 41:10, 13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa ṣe fún àwọn ọ̀rẹ́ òun?

  • Ṣó o rò pé ọ̀rẹ́ tó dáa ni Jèhófà? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá nílò ìrànwọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́

7. Tó o bá fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà, o gbọ́dọ̀ máa bá a sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo, kó o sì máa tẹ́tí sí i

Bí àwọn ọ̀rẹ́ bá ṣe ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tó ni wọ́n á ṣe túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Ka Sáàmù 86:6, 11, lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ọ̀nà wo la lè gbà bá Jèhófà sọ̀rọ̀?

  • Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà bá wa sọ̀rọ̀?

A máa ń bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àdúrà, òun náà sì máa ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Bíbélì

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò ṣeé ṣe fún àwa èèyàn láti di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.”

  • Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà láti fi hàn pé a lè di ọ̀rẹ́ Jèhófà?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Jèhófà fẹ́ di ọ̀rẹ́ rẹ, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Kí lo rí kọ́?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń ran àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́?

  • Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé káwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe àwọn àyípadà kan?

  • Ṣó o rò pé Jèhófà ń retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ rẹ kó o tó lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Àǹfààní wo lo máa rí tó o bá jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọlọ́run?

“Jèhófà​—Ọlọ́run Tó Yẹ Ká Mọ̀ Dáadáa” (Ilé Ìṣọ́, February 15, 2003)

Kà nípa bí ìgbésí ayé obìnrin kan ṣe dáa gan-an torí pé ó jẹ́ ọ̀rẹ́ Jèhófà.

“Mi Ò Fẹ́ Kú O!” (Ilé Ìṣọ́ No. 1 2017)

Gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ kan sọ nípa Jèhófà.

Àǹfààní Wo Ló Máa Ṣe Ẹ́ Tó O Bá Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run? (1:46)