Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 09

Máa Gbàdúrà Kó O Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run

Máa Gbàdúrà Kó O Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ṣé o ti rò ó rí pé o nílò ìtọ́sọ́nà nígbèésí ayé rẹ? Ṣé o ní àwọn ìbéèrè pàtàkì tó ò ń wá ìdáhùn wọn? Ṣé o nílò ìtùnú àti ìfọ̀kànbalẹ̀? Ṣé ó wù ẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? Àdúrà máa jẹ́ kí ọwọ́ rẹ lè tẹ gbogbo nǹkan yìí. Àmọ́, ọ̀nà wo ló tọ́ láti máa gbàdúrà? Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run máa ń gbọ́? Kí ló yẹ kó o ṣe kó lè dá ẹ lójú pé ó máa gbọ́ àdúrà rẹ? Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa àdúrà.

1. Ta ló yẹ ká gbàdúrà sí, kí la sì lè sọ nínú àdúrà?

Jésù kọ́ wa pé Baba wa ọ̀run nìkan ni ká máa gbàdúrà sí. Kódà Jésù fúnra rẹ̀ gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà lọ́nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run . . . ’” (Mátíù 6:9) Tá a bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, a máa di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́.

Gbogbo nǹkan la lè torí ẹ̀ gbàdúrà. Àmọ́ kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa, ó gbọ́dọ̀ bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Bíbélì sọ pé: “Tí a bá béèrè ohunkóhun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, ó ń gbọ́ wa.” (1 Jòhánù 5:14) Jésù sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká máa fi sínú àdúrà wa. (Ka Mátíù 6:9-13.) Kì í ṣe àwọn nǹkan tá à ń fẹ́ nìkan ló yẹ ká máa fi sínú àdúrà wa, ó tún yẹ ká máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run torí àwọn nǹkan tó ń ṣe fún wa, ká sì máa bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn míì lọ́wọ́.

2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?

Bíbélì sọ pé ká máa “tú ọkàn [wa] jáde níwájú [Ọlọ́run].” (Sáàmù 62:8) Torí náà, ó yẹ ká máa gbàdúrà látọkàn wá. A lè gbàdúrà sókè tàbí ká gbà á sínú. Ipò èyíkéyìí tó ń fi ọ̀wọ̀ hàn la lè wà tá a bá ń gbàdúrà. Kò sígbà tá ò lè gbàdúrà, bẹ́ẹ̀ ni kò síbi tá ò ti lè gbàdúrà.

3. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń dáhùn àdúrà?

Oríṣiríṣi ọ̀nà ni Jèhófà ń gbà dáhùn àdúrà wa. Lára ọ̀nà tó ń gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ó fún wa ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, inú ẹ̀ la ti ń rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè wa. Bíbélì kíkà máa ń “sọ aláìmọ̀kan di ọlọ́gbọ́n.” (Sáàmù 19:7; ka Jémíìsì 1:5.) Jèhófà máa ń jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ nígbà ìṣòro. Ó sì lè mú káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ lásìkò tá a nílò nǹkan kan.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè gbàdúrà àtọkànwá tínú Ọlọ́run máa dùn sí àti bí àdúrà ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní.

4. Ohun tó yẹ ká ṣe kí Ọlọ́run lè gbọ́ àdúrà wa

Àwọn nǹkan wo ló máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà wa tàbí kò ní gbọ́? Wo FÍDÍÒ yìí.

Jèhófà fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun. Ka Sáàmù 65:2. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé o rò pé “Olùgbọ́ àdúrà” fẹ́ kó o máa gbàdúrà sí òun? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Ka Míkà 3:4 àti 1 Pétérù 3:12. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wa, kí ló yẹ ká máa ṣe?

Tí ẹgbẹ́ ológun méjì bá fẹ́ jagun, àwọn méjèèjì ló máa ń gbàdúrà pé káwọn ṣẹ́gun. Ṣó wá bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run máa dáhùn àwọn àdúrà wọn?

5. Ó yẹ ká máa gbàdúrà látọkàn wá

Àwọn kan wà tó jẹ́ pé wọ́n ti kọ́ wọn láti máa gbàdúrà àkọ́sórí, ọ̀rọ̀ kan náà ni wọ́n sì máa ń lò ṣáá nínú àdúrà wọn. Ṣé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa gbàdúrà sí òun nìyẹn? Ka Mátíù 6:7. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí lo lè ṣe kó o lè yẹra fún sísọ “ohun kan náà ní àsọtúnsọ” nínú àdúrà rẹ?

Lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, o lè ronú nípa oore kan tí Jèhófà ṣe fún ẹ, kó o sì dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ fún oore náà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ lójoojúmọ́ fún ọ̀sẹ̀ kan, á jẹ́ pé o ti gbàdúrà nípa ohun méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nìyẹn láìjẹ́ pé ò ń tún ọ̀rọ̀ kan náà sọ.

Inú bàbá kan tó nífẹ̀ẹ́ ọmọ rẹ̀ máa dùn tí ọmọ náà bá sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún un. Inú Jèhófà náà máa ń dùn tá a bá ń gbàdúrà sí i látọkàn wá

6. Àdúrà jẹ́ ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run

Báwo ni àdúrà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tí nǹkan bá ń lọ dáadáa àti nígbà ìṣòro? Wo FÍDÍÒ yìí.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ń gbàdúrà, ọkàn wa máa balẹ̀ gan-an. Ka Fílípì 4:6, 7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìgbà gbogbo kọ́ ni àdúrà máa ń mú ìṣòro wa kúrò pátápátá, báwo ni àdúrà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

  • Àwọn nǹkan wo ló wù ẹ́ kó o béèrè nínú àdúrà rẹ?

Ǹjẹ́ o mọ̀?

Ọ̀rọ̀ náà “àmín” túmọ̀ sí “kí ó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “dájúdájú.” Láti ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì ni wọ́n ti máa ń sọ “àmín” ní ìparí àdúrà.​—1 Kíróníkà 16:36.

7. Máa wá àkókò tí wàá fi gbàdúrà

Nígbà míì ọwọ́ wa máa ń dí débi tá ò fi ní rántí gbàdúrà. Báwo ni àdúrà ti ṣe pàtàkì sí Jésù tó? Ka Mátíù 14:23 àti Máàkù 1:35, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni Jésù ṣe kó lè wá àyè láti gbàdúrà?

  • Àwọn ìgbà wo lo lè rí àyè láti fi gbàdúrà?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò síṣẹ́ gidi kan tí àdúrà ń ṣe jàre.”

  • Kí lèrò tìẹ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tá a bá ń gbàdúrà látọkàn wá, ó máa jẹ́ ká sún mọ́ Ọlọ́run, ó máa jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀, ó sì máa fún wa lókun ká lè ṣe ìfẹ́ Jèhófà.

Kí lo rí kọ́?

  • Ta ló yẹ ká máa gbàdúrà sí?

  • Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?

  • Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá ń gbàdúrà?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo ìdáhùn àwọn ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa àdúrà.

“Ohun Méje Tó Yẹ Kó O Mọ̀ Nípa Àdúrà” (Ilé Ìṣọ́, October 1, 2010)

Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o máa gbàdúrà àti bó o ṣe lè mú kí àdúrà rẹ dáa sí i.

“Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa ẹni tó yẹ ká máa gbàdúrà sí.

“Ṣó Yẹ Kí N Máa Gbàdúrà sí Àwọn Ẹni Mímọ́?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Nínú fídíò orin yìí, wò ó bóyá ó pọn dandan ká wà níbì kan pàtó ká tó lè gbàdúrà tàbí bóyá ó pọn dandan kó jẹ́ àkókò kan pàtó.

Gbàdúrà Nígbà Gbogbo (1:22)