Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 18

Bá A Ṣe Lè Mọ Àwọn Kristẹni Tòótọ́

Bá A Ṣe Lè Mọ Àwọn Kristẹni Tòótọ́

Àìmọye èèyàn ló sọ pé Kristẹni làwọn. Àmọ́ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ìlànà tí wọ́n ń tẹ̀ lé yàtọ̀ síra. Torí náà, báwo la ṣe lè mọ àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́?

1. Àwọn wo ni Kristẹni?

Àwọn Kristẹni ni àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù Kristi. (Ka Ìṣe 11:26.) Báwo ni wọ́n ṣe ń fi hàn pé ọmọ ẹ̀yìn Jésù làwọn? Jésù sọ pé: “Tí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín lóòótọ́.” (Jòhánù 8:31) Ohun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ òun. Inú Ìwé Mímọ́ ni ẹ̀kọ́ tí Jésù fi ń kọ́ àwọn èèyàn ti wá. Bákan náà, inú Bíbélì ni ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ ti wá.​—Ka Lúùkù 24:27.

2. Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn?

Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí mo ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.” (Jòhánù 15:12) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Ó lo àkókò pẹ̀lú wọn, ó fún wọn níṣìírí, ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Kódà, ó kú nítorí wọn. (1 Jòhánù 3:16) Lọ́nà kan náà, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń ṣe bíi ti Jésù, kì í ṣe ẹnu lásán ni wọ́n fi ń sọ pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Wọ́n máa ń fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wọn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn.

3. Iṣẹ́ wo làwọn Kristẹni tòótọ́ gbájú mọ́?

Jésù gbé iṣẹ́ kan lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́. “Ó rán wọn jáde láti wàásù Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 9:2) Kì í ṣe ilé ìjọsìn wọn nìkan làwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ ti wàásù, wọ́n tún lọ wàásù fáwọn èèyàn nílé wọn àti láwọn ibòmíì tí wọ́n bá ti rí àwọn èèyàn. (Ka Ìṣe 5:42; 17:17.) Bákan náà, lóde òní àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níbikíbi tí wọ́n bá ti rí àwọn èèyàn. Torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wọn, wọ́n máa ń fayọ̀ lo àkókò àti okun wọn láti tù wọ́n nínú, wọ́n sì ń jẹ́ kí wọ́n nírètí pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.​—Máàkù 12:31.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ àtàwọn tí kì í tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ àti àpẹẹrẹ Jésù.

4. Wọ́n ń wá òtítọ́ látinú Bíbélì

Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kì í ṣe gbogbo àwọn tó ń pe ara wọn ní Kristẹni ló ń fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ Bíbélì. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Kí làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kan tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni ṣe káwọn èèyàn máa bàa mọ ẹ̀kọ́ tí Jésù kọ́ni?

Jésù kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ka Jòhánù 18:37, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Bí Jésù ṣe sọ, báwo la ṣe lè mọ àwọn Kristẹni tó “fara mọ́ òtítọ́”?

5. Wọ́n ń wàásù òtítọ́ látinú Bíbélì

Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ wàásù fáwọn èèyàn

Kí Jésù tó pa dà sí ọ̀run, ó gbé iṣẹ́ kan lé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́, iṣẹ́ náà ò sì dáwọ́ dúró títí dòní. Ka Mátíù 28:19, 20 àti Ìṣe 1:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe máa gbòòrò tó?

6. Ìwà wọn bá ohun tí wọ́n ń wàásù mu

Kí ló mú kí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tom gbà pé òun ti rí ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, kí ló mú kí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sú Tom?

  • Kí ló mú kó gbà pé òun ti rí àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́?

Ìwà wa máa ń sọ irú ẹni tá a jẹ́ ju ọ̀rọ̀ ẹnu wa lọ. Ka Mátíù 7:21, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé ohun tá a sọ pé a jẹ́ ló ṣe pàtàkì jù sí Jésù ni àbí ohun tá à ń ṣe?

7. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn

Àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara wọn

Ṣé òótọ́ ni pé àwọn Kristẹni kan ṣe tán láti kú nítorí àwọn Kristẹni bíi tiwọn? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, kí ló mú kí Lloyd ṣe tán láti kú nítorí Arákùnrin Johansson?

  • Ṣé o rò pé ohun tí Lloyd ṣe yẹn fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni?

Ka Jòhánù 13:34, 35, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ló ṣe yẹ káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ (ìyẹn àwọn Kristẹni tòótọ́) máa hùwà sáwọn tó wá láti ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè míì?

  • Nígbà ogun, báwo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe lè fi hàn pé àwọn fẹ́ràn àwọn tó wá láti ẹ̀yà tàbí orílẹ̀-èdè míì?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Àwọn Kristẹni ti ṣe àwọn nǹkan tó burú gan-an, torí náà ẹ̀sìn wọn ò lè jẹ́ ẹ̀sìn tòótọ́.”

  • Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà fún ẹnì kan tó máa jẹ́ kó mọ bó ṣe lè dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ṣe ohun tí Bíbélì sọ, wọ́n máa ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn kódà láwọn ìgbà tí kò bá rọrùn, ohun tí Bíbélì kọ́ni ni wọ́n sì máa ń wàásù.

Kí lo rí kọ́?

  • Orí kí ni ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ dá lé?

  • Kí ni Bíbélì sọ pé a máa fi dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀?

  • Iṣẹ́ pàtàkì wo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ gbájú mọ́?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo fídíò yìí kó o lè túbọ̀ mọ àwọn tó ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù àti ẹ̀kọ́ rẹ̀.

Ta Ni Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (1:13)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí obìnrin kan tó jẹ́ mọdá ní ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tẹ́lẹ̀ gbà pé òun ti rí “àwọn èèyàn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.”

“Bíbélì Ni Wọ́n Fi Dáhùn Gbogbo Ìbéèrè Mi!” (Ilé Ìṣọ́, April 1, 2014)

Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń fìfẹ́ hàn sí ara wọn nígbà àjálù.

Bá A Ṣe Ń Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́ Nígbà Àjálù​—Àyọlò (3:57)

Ka ìwé yìí kó o lè rí bí àwọn Kristẹni àkọ́bẹ̀rẹ̀ àtàwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní ṣe ń ṣe ohun tí Jésù sọ pé àwọn èèyàn á fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀.

“Kí La Lè Fi Dá Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Mọ̀?” (IIé Ìṣọ́, March 1, 2012)