Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 19

Ṣé Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ṣé Kristẹni Tòótọ́ Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Kristẹni tòótọ́ ni wá. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká wo ohun mẹ́ta yìí: ohun tá a gbà gbọ́, orúkọ tá à ń jẹ́ àti ìfẹ́ tó wà láàárín wa.

1. Orí kí ni ẹ̀kọ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá lé?

Jésù sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ [Ọlọ́run].” (Jòhánù 17:17) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà gbà pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé bíi ti Jésù orí Bíbélì ni ẹ̀kọ́ wa dá lé. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ kan nínú ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní nǹkan bí ọdún 1870, àwùjọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bẹ̀rẹ̀ sí í fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n gbà gbọ́, kódà tó bá tiẹ̀ yàtọ̀ sí ẹ̀kọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n sì máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí wọ́n kọ́ látinú Bíbélì. a

2. Kí nìdí tá a fi ń jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Jèhófà máa ń pe àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ ní ẹlẹ́rìí òun torí wọ́n máa ń sọ òtítọ́ nípa rẹ̀. (Hébérù 11:4–12:1) Bí àpẹẹrẹ, nígbà àtijọ́ Ọlọ́run sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi.” (Ka Àìsáyà 43:10.) Bíbélì pe Jésù ní “Ẹlẹ́rìí Olóòótọ́.” (Ìfihàn 1:5) Nítorí náà, lọ́dún 1931 a bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú wa dùn pé à ń jẹ́ orúkọ yẹn.

3. Báwo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ hàn bíi ti Jésù?

Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gan-an débi tó fi sọ pé ìdílé òun ni wọ́n. (Ka Máàkù 3:35.) Lọ́nà kan náà, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìdílé tó wà níṣọ̀kan kárí ayé. Ìdí nìyẹn tá a fi ń pe ara wa ní arákùnrin àti arábìnrin. (Fílémónì 1, 2) A tún máa ń ṣègbọràn sí àṣẹ tó sọ pé: “Ẹ máa nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn ará.” (1 Pétérù 2:17) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn lónírúurú ọ̀nà, bí àpẹẹrẹ, a máa ń ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa kárí ayé lọ́wọ́ tí wọ́n bá níṣòro.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Fara balẹ̀ ka ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kó o lè túbọ̀ rí ẹ̀rí tó fi hàn pé Kristẹni tòótọ́ ni wá.

Ohun tó wà nínú Bíbélì ni àwọn Kristẹni tòótọ́ gbà gbọ́, òun ni wọ́n sì fi ń kọ́ àwọn èèyàn

4. Orí Bíbélì ni ẹ̀kọ́ wa dá lé

Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá di àkókò òpin, ẹ̀kọ́ Bíbélì máa túbọ̀ yé wa. Ka Dáníẹ́lì 12:4 àti àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló máa ‘pọ̀ gan-an’ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run bí wọ́n ṣe ń yẹ Bíbélì wò fínnífínní?

Wo ọ̀nà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan gbà kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀kan lára wọn ni Charles Russell. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, ọ̀nà wo ni Arákùnrin Charles Russell àtàwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Ǹjẹ́ o mọ̀?

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, a máa ń ṣàtúnṣe àwọn kan lára ohun tá a gbà gbọ́. Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo àpèjúwe yìí: Tí ilẹ̀ bá ń mọ́ bọ̀, díẹ̀díẹ̀ la máa ń rí àwọn ohun tó wà láyìíká wa títí dìgbà tílẹ̀ á fi mọ́ kedere. Lọ́nà kan náà, ńṣe ni Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀ síwájú sí i. (Ka Òwe 4:18.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò yí pa dà, a máa ń ṣàtúnṣe àwọn ohun tá a gbà gbọ́ bá a ṣe ń lóye Bíbélì sí i.

5. Orúkọ wa ń rò wá

Kí nìdí tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Kí nìdí tó fi jẹ́ pé orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló yẹ wá?

Kí nìdí tí Jèhófà fi yan àwọn èèyàn kan láti jẹ́ ẹlẹ́rìí rẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ló máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, torí pé àwọn èèyàn máa ń sọ oríṣiríṣi ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa Ọlọ́run. Wo méjì lára àwọn ohun tí wọ́n máa ń sọ.

Àwọn ẹlẹ́sìn kan ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn pé Ọlọ́run fẹ́ kí wọ́n máa lo ère nínú ìjọsìn wọn. Jẹ́ ká wò ó bóyá Ọlọ́run fẹ́ bẹ́ẹ̀ lóòótọ́. Ka Léfítíkù 26:1, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé Jèhófà fẹ́ ká máa fi ère jọ́sìn òun? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Àwọn olórí ẹ̀sìn kan ń kọ́ àwọn èèyàn pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè. Jẹ́ ká wò ó bóyá Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè lóòótọ́. Ka Jòhánù 20:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé ẹnì kan náà ni Ọlọ́run àti Jésù? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

  • Báwo ló ṣe rí lára ẹ bó o ṣe mọ̀ pé Jèhófà ti rán àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti máa wàásù ohun tó jóòótọ́ nípa òun àti Ọmọ rẹ̀?

6. A nífẹ̀ẹ́ ara wa

Bíbélì fi àwọn Kristẹni wé ẹ̀yà ara èèyàn. Ka 1 Kọ́ríńtì 12:25, 26, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló yẹ káwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe tí ìyà bá ń jẹ àwọn kan lára wọn?

  • Kí lo kíyè sí nípa irú ìfẹ́ tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lápá ibì kan láyé bá ń jìyà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kù kárí ayé máa ń dìde ìrànwọ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kó o lè rí àpẹẹrẹ kan, wo FÍDÍÒ yìí. lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Báwo ni ìrànwọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe nígbà àjálù ṣe fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ẹ̀sìn tuntun ni ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

  • Látìgbà wo ni Jèhófà ti ń pe àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ ní ẹlẹ́rìí òun?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Kristẹni tòótọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìdílé kan tó ń jọ́sìn Jèhófà kárí ayé ni wá, inú Bíbélì ni àwọn ẹ̀kọ́ wa ti wá, a sì ń sọ òtítọ́ nípa Jèhófà fáwọn èèyàn.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tá a fi bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ́ orúkọ náà, Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

  • Báwo la ṣe máa ń ṣe sí ara wa?

  • Ṣé o rò pé Kristẹni tòótọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo fídíò yìí kó o lè rí àpẹẹrẹ bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe tú àṣírí ẹ̀kọ́ èké.

Àwọn Èèyàn Ọlọ́run Ń Gbé Orúkọ Rẹ̀ Ga (7:08)

Tí ohun kan bá wà tó o fẹ́ mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, lọ ka àpilẹ̀kọ yìí.

“Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Máa Ń Béèrè Nípa Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Stephen kórìíra àwọn ẹ̀yà míì débí pé ó máa ń gbéjà kò wọ́n. Ka ìwé yìí, kó o lè mọ ohun tó rí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó mú kó yí ìwà rẹ̀ pa dà.

“Ìwà Burúkú Ọwọ́ Mi Ń Peléke Sí I” (Ilé Ìṣọ́, July 1, 2015)

a Ilé Ìṣọ́ ni ìwé tó gbawájú tá a fi ń kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fáwọn èèyàn, látọdún 1879 la sì ti ń tẹ̀ ẹ́ jáde.