Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 25

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?

Bíbélì sọ pé ‘ọlọ́jọ́ kúkúrú ni àwa èèyàn, wàhálà tá à ń dojú kọ sì pọ̀ gan-an.’ (Jóòbù 14:1) Ṣé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí nǹkan rí fún wa nìyí? Tó bá jẹ́ pé ohun tó fẹ́ kọ́ nìyẹn, kí wá nìdí tó fi dá wa? Ṣé ayé ṣì máa rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́? Jẹ́ ká wo ohun tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa èyí.

1. Irú ìgbésí ayé wo ni Ọlọ́run ń fẹ́ fún wa?

Ìgbésí ayé tó dáa jù lọ ni Jèhófà ń fẹ́ fún wa. Nígbà tí Jèhófà dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sínú Párádísè kan tó rẹwà, tí Bíbélì pè ní ọgbà Ẹ́dẹ́nì. Lẹ́yìn náà, “Ọlọ́run súre fún wọn, Ọlọ́run sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa bímọ, kí ẹ sì pọ̀, kí ẹ kún ayé, kí ẹ sì ṣèkáwọ́ rẹ̀.’” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Jèhófà fẹ́ kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sọ gbogbo ayé di Párádísè, kí wọ́n sì máa bójú tó àwọn ẹranko. Ó fẹ́ kí àwa èèyàn ní ìlera pípé, ká sì wà láàyè títí láé.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ayé ò tíì rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, a àwọn ohun rere tó ní lọ́kàn láti ṣe fún wa kò tíì yí pa dà. (Àìsáyà 46:10, 11) Ó ṣì fẹ́ káwọn onígbọràn máa gbé ayé títí láé, láìsí ìṣòro kankan.​—Ka Ìfihàn 21:3, 4.

2. Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ gbé ìgbé ayé tó dáa ní báyìí?

Jèhófà dá wa lọ́nà tó fi máa ń wù wá láti wá “ìtọ́sọ́nà” rẹ̀. Ìdí nìyẹn tá a fi ń fẹ́ láti mọ̀ ọ́n, ká sì máa jọ́sìn rẹ̀. (Ka Mátíù 5:3-6.) Ó fẹ́ ká sún mọ́ òun dáadáa, ká máa “rìn ní gbogbo ọ̀nà” òun, ká máa “nífẹ̀ẹ́” òun, ká sì máa sin òun pẹ̀lú “gbogbo ọkàn” wa. (Diutarónómì 10:12; Sáàmù 25:14) Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa ní ayọ̀ tòótọ́, láìka àwọn ìṣòro wa sí. Tá a bá ń sin Jèhófà, ayé wa máa dáa, ọkàn wa sì máa balẹ̀.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo bí ọ̀nà tí Jèhófà gbà dá ayé yìí ṣe fi hàn pé ó nífẹ̀ẹ́ wa gan-an àti ohun tí Bíbélì sọ nípa ìdí tí Jèhófà fi dá wa.

3. Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa

Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Kí nìdí tí Ọlọ́run fi dá ayé yìí lọ́nà tó rẹwà?

Ka Oníwàásù 3:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Bí ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe sọ, kí ni Jèhófà ń fẹ́ fún wa?

4. Jèhófà ṣì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé

Ka Sáàmù 37:11, 29 àti Àìsáyà 55:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà ṣì máa ṣe ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé?

5. Tá a bá ń sin Jèhófà, ayé wa máa dáa

Tá a bá mọ ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa, ọkàn wa máa balẹ̀. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Àǹfààní wo ni Terumi rí nígbà tó mọ ìdí tá a fi wà láyé?

Ka Oníwàásù 12:13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tá a bá ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, kí ló yẹ ká máa ṣe láti fi hàn pé a moore?

ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí nìdí tá a fi wà láyé?”

  • Kí lo máa sọ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Jèhófà fẹ́ ká máa gbádùn ayé wa títí láé, láìsí ìṣòro kankan. Tá a bá ń sìn ín tọkàntọkàn, kódà ní báyìí, ayé wa máa dùn, ọkàn wa sì máa balẹ̀.

Kí lo rí kọ́?

  • Irú ìgbé ayé wo ni Jèhófà fẹ́ kí Ádámù àti Éfà máa gbé?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún aráyé ò tíì yí pa dà?

  • Kí la lè ṣe tí ayé wa á fi dáa?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ka ìwé yìí kó o lè rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ọgbà Édẹ́nì wà lóòótọ́.

“Ọgbà Édẹ́nì, Ṣé Ó Wà Lóòótọ́ Àbí Àròsọ Ni?” (Ilé Ìṣọ́, January 1, 2011)

Ka ìwé yìí kó o lè rí ìdí tó fi dá wa lójú pé ayé yìí máa wà títí láé.

“Ṣé Ilẹ̀ Ayé Máa Pa Run?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ pé a lè ṣe tí ayé wa á fi dáa.

“Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Dá Wa?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí ọkùnrin kan tó rò pé òun ti ní gbogbo nǹkan tán ṣe wá rí i pé ohun pàtàkì kan wà tóun ò tíì ní.

Ní Báyìí, Ohun Tó Dára Ni Mò Ń Fi Ayé Mi Ṣe (3:55)

a Nínú ẹ̀kọ́ tó kàn, o máa mọ ohun tó fà á tí ayé ò fi tíì rí bí Ọlọ́run ṣe fẹ́.