Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 31

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run ni ohun pàtàkì tí Bíbélì dá lé. Ìjọba yẹn ni Jèhófà máa lò láti sọ ayé di Párádísè pa dà. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run? Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ti ń ṣàkóso báyìí? Àwọn nǹkan wo ló ti ṣe? Àwọn nǹkan wo ló sì máa ṣe lọ́jọ́ iwájú? A máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí nínú ẹ̀kọ́ yìí àtàwọn ẹ̀kọ́ méjì tó tẹ̀ lé e.

1. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run, ta sì ni Ọba Ìjọba náà?

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Jèhófà Ọlọ́run gbé kalẹ̀ ní ọ̀run. Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba náà, àtọ̀run ló sì ti ń ṣàkóso. (Mátíù 4:17; Jòhánù 18:36) Bíbélì sọ pé Jésù “máa jẹ Ọba . . . títí láé.” (Lúùkù 1:32, 33) Torí pé Jésù ni Ọba Ìjọba Ọlọ́run, ó máa ṣàkóso gbogbo àwọn tó wà láyé.

2. Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù?

Jésù nìkan kọ́ ló máa dá ṣàkóso. Àwọn èèyàn látinú “gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè . . . máa ṣàkóso bí ọba lé ayé lórí.” (Ìfihàn 5:9, 10) Àwọn mélòó ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi? Látìgbà tí Jésù ti wá sáyé, àìmọye èèyàn ló ti di Kristẹni. Àmọ́, àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) péré lára wọn ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. (Ka Ìfihàn 14:1-4.) Gbogbo àwọn Kristẹni tó kù láyé sì máa jẹ́ ọmọ Ìjọba Ọlọ́run.​—Sáàmù 37:29.

3. Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ìjọba èèyàn lọ?

Nígbà míì, a lè rí àwọn kan lára àwọn tó ń ṣàkóso tí wọ́n ń gbìyànjú láti ṣohun tó dáa fáwọn aráàlú, àmọ́ agbára wọn kì í gbé e láti ṣe gbogbo ohun tó dáa tí wọ́n ní lọ́kàn. Tó bá yá, ẹlòmíì á rọ́pò wọn, onítọ̀hún sì lè má ní ire ará ìlú lọ́kàn. Àmọ́ ní ti Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run, kò sẹ́ni tó lè rọ́pò ẹ̀ tàbí tó lè gba ìjọba lọ́wọ́ ẹ̀. Ọlọ́run ti “gbé ìjọba kan kalẹ̀, tí kò ní pa run láé.” (Dáníẹ́lì 2:44) Gbogbo ayé ni Jésù máa ṣàkóso, kò sì ní ṣojúsàájú. Kò mọ síbẹ̀ o, ó nífẹ̀ẹ́ wa, olóore ni, ìdájọ́ òdodo ló máa ń ṣe, ó sì máa kọ́ àwọn èèyàn pé káwọn náà nífẹ̀ẹ́ àwọn míì, kí wọ́n máa ṣoore, kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo.​—Ka Àìsáyà 11:9.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo ìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi dáa ju ìjọba èèyàn lọ.

4. Ìjọba kan tó lágbára máa ṣàkóso gbogbo ayé

Jésù lágbára ju gbogbo àwọn tó ti ṣàkóso láyé lọ. Ka Mátíù 28:18, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló mú kí àṣẹ Jésù ju ti àwọn èèyàn tó jẹ́ alákòóso lọ?

Ní ti ìjọba èèyàn, tẹ́nì kan bá ṣàkóso lónìí, ẹlòmíì á gbà á lọ́la, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ló sì ti ní apá ibi tí àkóso ẹ̀ dé. Àmọ́ Ìjọba Ọlọ́run ńkọ́? Ka Dáníẹ́lì 7:14, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tó fi dáa gan-an pé Ìjọba Ọlọ́run ‘kò ní pa run’?

  • Kí nìdí tó fi dáa gan-an pé gbogbo ayé ni Ìjọba Ọlọ́run á máa ṣàkóso?

5. Ìjọba èèyàn gbọ́dọ̀ dópin

Kí nìdí tí Ìjọba Ọlọ́run fi gbọ́dọ̀ rọ́pò ìjọba èèyàn? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Àkóbá wo ni ìjọba èèyàn ti ṣe fún aráyé?

Ka Oníwàásù 8:9, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé o gbà pé ó yẹ kí Ìjọba Ọlọ́run rọ́pò ìjọba èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

6. Ọ̀rọ̀ wa yé Jésù àtàwọn tó máa bá a ṣàkóso

Torí pé Jésù Ọba wa ti gbé ayé rí gẹ́gẹ́ bí èèyàn, ó lè “bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.” (Hébérù 4:15) Bákan náà, “látinú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn àti orílẹ̀-èdè” ni Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin olóòótọ́ tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí wọ́n máa bá Jésù ṣàkóso.​—Ìfihàn 5:9.

  • Ṣé ọkàn ẹ balẹ̀ bó o ṣe mọ̀ pé Jésù àti gbogbo àwọn tó máa bá a ṣàkóso mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwa èèyàn? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Jèhófà ti yan àwọn ọkùnrin àti obìnrin látinú gbogbo ẹ̀yà àti orílẹ̀-èdè láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù

7. Àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ti ìjọba èèyàn lọ

Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Bákan náà, Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn òfin tí àwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run náà gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé. Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9-​11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Báwo lo ṣe rò pé ayé máa rí lọ́jọ́ iwájú nígbà tí gbogbo èèyàn bá ń tẹ̀ lé àwọn òfin Ọlọ́run? a

  • Ṣé o rò pé ó bọ́gbọ́n mu bí Jèhófà ṣe sọ pé káwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa tẹ̀ lé àwọn òfin yìí? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé àwọn tí kì í tẹ̀ lé àwọn òfin yìí lè yí pa dà?​—Wo ẹsẹ 11.

Ìjọba èèyàn máa ń ṣe àwọn òfin tí wọ́n gbà pé ó máa ṣe aráàlú láǹfààní tó sì máa dáàbò bò wọ́n. Àmọ́ àwọn òfin Ìjọba Ọlọ́run ṣàǹfààní gan-an ju ti ìjọba èèyàn lọ

ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?”

  • Kí lo máa sọ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ gbé kalẹ̀ ní ọ̀run, ó sì máa ṣàkóso lórí gbogbo ayé.

Kí lo rí kọ́?

  • Àwọn wo ló máa jẹ́ alákòóso Ìjọba Ọlọ́run?

  • Kí ló mú kí Ìjọba Ọlọ́run dáa ju ìjọba èèyàn lọ?

  • Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan ti Jèhófà fẹ́ káwọn ọmọ Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ka ìwé yìí kó o lè mọ ibi tí Jésù sọ pé Ìjọba Ọlọ́run wà.

“Ṣé Inú Ọkàn Rẹ Ni Ìjọba Ọlọ́run Wà?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Ìjọba Ọlọ́run làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fi gbogbo ọkàn wa tì lẹ́yìn dípò ìjọba èèyàn?

Ìjọba Ọlọ́run Ni Wọ́n Fara Mọ́ (1:43)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) tí Jèhófà yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù.

“Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Kí ló mú kí obìnrin kan tó wà lẹ́wọ̀n gbà pé Ọlọ́run nìkan ló lè mú ìrẹ́jẹ kúrò láyé?

“Mo Ti Wá Mọ Bí Àìṣẹ̀tọ́ Ṣe Máa Dópin” (Jí!, July-September, 2011)

a A máa ṣàlàyé àwọn kan lára òfin yìí tá a bá dé Apá 3.