Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 39

Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀

Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀

Ẹ̀jẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an. Láìsí ẹ̀jẹ̀, kò sẹ́nì kankan nínú wa tó lè wà láàyè. Torí pé Ọlọ́run ni Ẹlẹ́dàá wa, ó lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ bó ṣe yẹ ká máa lo ẹ̀jẹ̀. Kí ni Ọlọ́run sọ nípa ẹ̀jẹ̀? Ṣé a lè jẹ ẹ́ tàbí ká fà á sínú ara wa? Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀jẹ̀?

1. Kí ni Jèhófà sọ nípa ẹ̀jẹ̀?

Nínú Bíbélì, Jèhófà sọ fáwọn olùjọsìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí gbogbo onírúurú ẹran.” (Léfítíkù 17:14) Lójú Jèhófà, ẹ̀jẹ̀ dúró fún ẹ̀mí. Bí ẹ̀mí ṣe jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye tí Ọlọ́run fún wa, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀jẹ̀ ṣe jẹ́ ohun iyebíye.

2. Àṣẹ wo ni Jèhófà pa fáwọn èèyàn rẹ̀ nípa ẹ̀jẹ̀?

Lẹ́yìn Ìkún Omi, Jèhófà pàṣẹ fáwọn olùjọsìn rẹ̀ pé kí wọ́n má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀. Nígbà tó yá, ó tún pàṣẹ yìí fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 9:4 àti Léfítíkù 17:10.) Jèhófà tún jẹ́ kí ìgbìmọ̀ olùdarí sọ fáwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pé kí wọ́n “máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀.”​—Ka Ìṣe 15:28, 29.

Kí ló túmọ̀ sí láti ta kété sí ẹ̀jẹ̀? Tí dókítà bá sọ fún ẹ pé kó o yẹra fún ọtí, ohun tó ń sọ ni pé kó o má ṣe mu ọtí mọ́. Àmọ́, ṣé wàá máa jẹ oúnjẹ tí wọ́n fi ọtí sínú ẹ̀ àbí wàá gbà kí wọ́n fa ọtí sí ẹ lára? Ó dájú pé o ò ní ṣe bẹ́ẹ̀. Bákan náà, àṣẹ tí Jèhófà pa pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀ túmọ̀ sí pé a ò gbọ́dọ̀ mu ẹ̀jẹ̀, a ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹran tí wọn ò dúńbú. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ oúnjẹ tí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ sínú ẹ̀.

Ṣé a lè fi ẹ̀jẹ̀ tọ́jú aláìsàn? Àwọn ọ̀nà kan wà tí wọ́n ń gbà fi ẹ̀jẹ̀ tójú aláìsàn tí kò bá òfin Ọlọ́run mu. Èyí sì kan gbígba ògidì ẹ̀jẹ̀ sára tàbí èyíkéyìí nínú àwọn èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sẹ́ẹ̀lì pupa, sẹ́ẹ̀lì funfun, sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì àti omi inú ẹ̀jẹ̀. Àmọ́, àwọn ọ̀nà míì wà táwọn dókítà máa ń gbà tọ́jú aláìsàn tí kò sí òfin tàbí ìlànà pàtó tó ta kò ó nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń fi ìpín tí wọ́n mú látara àwọn èròjà tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀ tọ́jú aláìsàn. Bákan náà, wọ́n máa ń lo ẹ̀jẹ̀ aláìsàn fúnra ẹ̀ láti tọ́jú ẹ̀. Ẹnì kọ̀ọ̀kàn ló máa pinnu ohun tó máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ yìí. a​—Gálátíà 6:5.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa tá a bá fẹ́ gba ìtọ́jú tó jẹ mọ́ lílo ẹ̀jẹ̀.

3. Ṣe ìpinnu tó máa múnú Jèhófà dùn tó o bá ń ṣàìsàn

Báwo lo ṣe lè ṣe ìpinnu tó bá òfin Ọlọ́run mu tó o bá ń ṣàìsàn? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ṣe àwọn ohun tó tẹ̀ lé e.

  • Bẹ Ọlọ́run pé kó fún ẹ ní ọgbọ́n. ​—Jémíìsì 1:5.

  • Ṣèwádìí nípa àwọn ìlànà Bíbélì tó bá ipò ẹ mu.​—Òwe 13:16.

  • Ṣèwádìí nípa àwọn ọ̀nà ìtọ́jú míì tí wọ́n máa ń ṣe lágbègbè ẹ.

  • Mọ àwọn ìtọ́jú tí kò yẹ kó o gbà rárá.

  • Rí i dájú pé ìpinnu tó máa jẹ́ kó o ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ lo ṣe.​—Ìṣe 24:16. b

  • Fi sọ́kàn pé tó bá dọ̀rọ̀ àwọn ìpinnu tó kan ẹ̀rí ọkàn, kò sẹ́nì kankan tó lè sọ ohun tó o máa ṣe fún ẹ, ì báà jẹ́ ọkọ ẹ, aya ẹ, àwọn alàgbà, tàbí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.​—Róòmù 14:12.

  • Kọ ìpinnu tó o fẹ́ ṣe síbì kan.

4. Ìtọ́jú tó dáa jù lọ làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń fẹ́ gbà

A lè gba ìtọ́jú tó dáa jù lọ láìrú òfin Ọlọ́run nípa ẹ̀jẹ̀. Wo FÍDÍÒ yìí.

Ka Títù 3:2, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún àwọn dókítà, ká sì ṣe sùúrù nígbà tá a bá ń bá wọn sọ̀rọ̀?

Èyí tá ò gbọ́dọ̀ gbà

Èyí tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan máa pinnu

A. Omi inú ẹ̀jẹ̀.

Ìpín látinú omi inú ẹ̀jẹ̀

B. Sẹ́ẹ̀lì funfun.

Ìpín látinú sẹ́ẹ̀lì funfun

D. Sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì.

Ìpín látinú sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì

E. Sẹ́ẹ̀lì pupa.

Ìpín látinú sẹ́ẹ̀lì pupa

 5. Ohun tó yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ kí wọ́n fi ìpín ẹ̀jẹ̀ tọ́jú ẹ

Èròjà mẹ́rin ló para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, àwọn sì ni sẹ́ẹ̀lì pupa, sẹ́ẹ̀lì funfun, sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì, àti omi inú ẹ̀jẹ̀. Àwọn èròjà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí tún ní ọ̀pọ̀ apá kéékèèké tí wọ́n ń pè ní ìpín ẹ̀jẹ̀. c Àwọn ìpín ẹ̀jẹ̀ kan wà táwọn dókítà máa ń lò láti gbógun ti àrùn tàbí tí wọ́n fi ń mú kí ẹ̀jẹ̀ tó ń dà jáde lára dáwọ́ dúró.

Tó bá kan ti àwọn ìpín ẹ̀jẹ̀, Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́ mu. Àwọn kan lè sọ pé àwọn ò fẹ́ kí wọ́n fi ìpín ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí tọ́jú àwọn. Àwọn míì sì lè sọ pé ẹ̀rí ọkàn àwọn gba àwọn láyè láti gba àwọn ìpín ẹ̀jẹ̀ sára.

Tó o bá fẹ́ pinnu ohun tó o máa ṣe, ronú lórí ìbéèrè yìí:

  • Tí mo bá fẹ́ bá dókítà sọ̀rọ̀, báwo ni mo ṣe lè ṣàlàyé ìdí tí mi ò fi fẹ́ kí wọ́n fi àwọn ìpín ẹ̀jẹ̀ kan tọ́jú mi tàbí ìdí tí mo fi gbà pé kí wọ́n fi àwọn ìpín ẹ̀jẹ̀ míì tọ́jú mi?

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn gba ẹ̀jẹ̀ sára?”

  • Kí lèrò tìẹ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Jèhófà ò fẹ́ ká máa lo ẹ̀jẹ̀ lọ́nà tí kò dáa.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tí Jèhófà fi ka ẹ̀jẹ̀ sí ohun iyebíye?

  • Báwo la ṣe mọ̀ pé àṣẹ tí Ọlọ́run pa pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀ kan gbígba ẹ̀jẹ̀ sára?

  • Tó o bá fẹ́ gba ìtọ́jú, báwo lo ṣe lè ṣe ìpinnu tó dáa nípa ẹ̀jẹ̀?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o fi sọ́kàn tó o bá fẹ́ káwọn dókítà lo ẹ̀jẹ̀ rẹ láti tọ́jú ẹ?

“Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” (Ilé Ìṣọ́, October 15, 2000)

Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn tó o bá fẹ́ káwọn dókítà fi ìpín látara èròjà ẹ̀jẹ̀ tọ́jú ẹ?

“Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” (Ilé Ìṣọ́, June 15, 2004)

Kí ló mú kí oníṣègùn kan gbà pé ohun tí Jèhófà sọ nípa ẹ̀jẹ̀ bọ́gbọ́n mu?

“Mo Fara Mọ́ Ohun Tí Ọlọ́run Sọ Nípa Ẹ̀jẹ̀” (Jí!, December 8, 2003)

Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn alàgbà tí wọ́n wà lára Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ṣe ń ran àwọn ará lọ́wọ́.

Jèhófà Máa Ń Bójú Tó Àwọn Tó Ń Ṣàìsàn (10:23)

a Wo Ẹ̀kọ́ 35, “Bá A Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dáa.”

b Wo  kókó 5, “Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Tó O Bá Fẹ́ Kí Wọ́n Fi Ìpín Ẹ̀jẹ̀ Tọ́jú Ẹ” àti Àlàyé Ìparí Ìwé 3, “Ohun Tó Yẹ Kó O Fi Sọ́kàn Tó O Bá Fẹ́ Gba Ìtọ́jú Tó Jẹ Mọ́ Lílo Ẹ̀jẹ̀.”

c Àwọn dókítà kan gbà pé ìpín ẹ̀jẹ̀ làwọn èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀. Torí náà, ó ṣe pàtàkì kó o ṣàlàyé fún dókítà ẹ pé o ò ní gbà kí wọ́n fa ògidì ẹ̀jẹ̀ sí ẹ lára. Bákan náà, o ò ní gbà kí wọ́n fa ògidì sẹ́ẹ̀lì pupa, sẹ́ẹ̀lì funfun, sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì, tàbí omi inú ẹ̀jẹ̀ sí ẹ lára.