Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 46

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ Fún Jèhófà Kó O sì Ṣèrìbọmi

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ Fún Jèhófà Kó O sì Ṣèrìbọmi

Tó o bá fẹ́ ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, wàá gbàdúrà sí i, wàá ṣèlérí fún un pé òun nìkan ni wàá máa sìn, ìfẹ́ rẹ̀ ni wàá sì fi sípò àkọ́kọ́ láyé rẹ. (Sáàmù 40:8) Lẹ́yìn náà, wàá ṣèrìbọmi káwọn èèyàn lè mọ̀ pé o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Ìpinnu tó ṣe pàtàkì jù téèyàn lè ṣe ni pé kó ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ìpinnu yìí sì máa yí ìgbésí ayé rẹ pa dà gan-an. Kí ló máa jẹ́ kó wù ẹ́ láti ṣe ìpinnu pàtàkì yìí?

1. Kí ló máa jẹ́ kó wu ẹnì kan láti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà?

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó máa wù wá láti ya ara wa sí mímọ́ fún un. (1 Jòhánù 4:10, 19) Bíbélì sọ pé: “Fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara rẹ àti gbogbo èrò rẹ àti gbogbo okun rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.” (Máàkù 12:30) Kì í ṣe ohun tá à ń sọ nìkan ló yẹ kó fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ó tún gbọ́dọ̀ hàn nínú ìwà àti ìṣe wa. Bí àpẹẹrẹ, tí ọkùnrin àti obìnrin tó ń fẹ́ra sọ́nà bá nífẹ̀ẹ́ ara wọn dénú, wọ́n á ṣègbéyàwó. Bákan náà, tẹ́nì kan bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lóòótọ́, á ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún un, á sì ṣèrìbọmi.

2. Àwọn nǹkan rere wo lẹni tó bá ṣèrìbọmi máa rí látọ̀dọ̀ Jèhófà?

Tó o bá ṣèrìbọmi, wàá di ara ìdílé Jèhófà, wàá sì máa láyọ̀. Jèhófà máa fìfẹ́ hàn sí ẹ lóríṣiríṣi ọ̀nà, ìyẹn á sì jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ ọn kódà ju bó o ṣe sún mọ́ ọn báyìí lọ. (Ka Málákì 3:16-​18.) Yàtọ̀ síyẹn, wàá rí Jèhófà bíi bàbá tó nífẹ̀ẹ́ rẹ, wàá tún ní àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin kárí ayé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. (Ka Máàkù 10:29, 30.) Àmọ́, kó o tó lè ṣèrìbọmi àwọn nǹkan kan wà tó o gbọ́dọ̀ ṣe. Ó yẹ kó o mọ irú ẹni tí Jèhófà jẹ́, kó o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, kó o sì gba Ọmọ rẹ̀ gbọ́. Lẹ́yìn náà, wàá ya ara ẹ sí mímọ́ fún Jèhófà. Tó o bá ṣe àwọn nǹkan yìí, tó o sì ṣèrìbọmi, wàá láǹfààní láti gbádùn ayé rẹ títí láé. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ìrìbọmi . . . tún ń gbà yín là báyìí.”​—1 Pétérù 3:21.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà kó o sì ṣèrìbọmi.

3. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló gbọ́dọ̀ pinnu ẹni tó máa sìn

Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, àwọn kan rò pé àwọn lè máa jọ́sìn Jèhófà kí wọ́n sì tún máa jọ́sìn òrìṣà Báálì. Àmọ́ Jèhófà rán wòlíì Èlíjà sí wọn láti jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìyẹn ò ṣe é ṣe. Ka 1 Àwọn Ọba 18:21, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Ìpinnu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní láti ṣe?

Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwa náà gbọ́dọ̀ pinnu ẹni tá a máa sìn. Ka Lúùkù 16:13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tá ò fi lè máa jọ́sìn Jèhófà ká sì tún máa jọ́sìn ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun míì?

  • Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé òun la fẹ́ sìn?

4. Ronú lórí bí Jèhófà ṣe fìfẹ́ hàn sí ẹ

Ọ̀pọ̀ nǹkan tó ṣeyebíye ni Jèhófà ti fún wa. Kí làwa náà lè fún Jèhófà? Wo FÍDÍÒ yìí.

Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà ti gbà fìfẹ́ hàn sí ẹ? Ka Sáàmù 104:14, 15 àti 1 Jòhánù 4:9, 10, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe fún ẹ tó o mọyì gan-an?

  • Kí làwọn nǹkan yẹn jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà?

Tí ẹ̀bùn kan bá ṣe pàtàkì sí wa, ó dájú pé a máa fẹ́ fi hàn pé a mọyì ẹni tó fún wa lẹ́bùn náà. Ka Diutarónómì 16:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni wàá fẹ́ fún Jèhófà tó o bá ronú nípa gbogbo nǹkan tó ti ṣe fún ẹ?

5. Wàá rí ọ̀pọ̀ ìbùkún tó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà

Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé àwọn máa láyọ̀ táwọn bá lókìkí, táwọn lówó rẹpẹtẹ tàbí níṣẹ́ gidi lọ́wọ́. Ṣé òótọ́ ni? Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin tá a rí nínú fídíò yìí fẹ́ràn láti máa gbá bọ́ọ̀lù, kí ló mú kó fiṣẹ́ náà sílẹ̀?

  • Ó kúrò nídìí iṣẹ́ bọ́ọ̀lù kó lè fayé ẹ̀ sin Jèhófà. Ṣé o rò pé ìpinnu tó ṣe yẹn bọ́gbọ́n mu? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Kí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó di Kristẹni, ṣe ló ń wá bóun ṣe máa di ẹni ńlá nínú ayé. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin àwọn Júù látọ̀dọ̀ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ tó gbajúmọ̀ jù lọ nígbà ayé rẹ̀. Àmọ́ ó fi gbogbo ẹ̀ sílẹ̀ kó lè di Kristẹni. Ṣé Pọ́ọ̀lù kábàámọ̀ ìpinnu tó ṣe yẹn? Ka Fílípì 3:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi pe àwọn nǹkan tó ṣe kó tó di Kristẹni ní “ọ̀pọ̀ pàǹtírí,” tàbí ìdọ̀tí?

  • Àǹfààní wo ló rí torí ìpinnu tó ṣe yẹn?

  • Ṣé o rò pé ayé rẹ máa nítumọ̀ tó o bá ń sin Jèhófà? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Àwọn ìbùkún tí Pọ́ọ̀lù rí lẹ́yìn tó di Kristẹni ju ohunkóhun tó yááfì lọ

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Kò bọ́gbọ́n mu kéèyàn fayé ẹ̀ sin Ọlọ́run.”

  • Kí nìdí tó o fi gbà pé ó bọ́gbọ́n mu kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, a máa ya ara wa sí mímọ́ fún un, àá sì ṣèrìbọmi.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì máa jọ́sìn rẹ̀?

  • Báwo ni Jèhófà ṣe máa ń bù kún àwọn tó ṣèrìbọmi?

  • Ṣé wàá fẹ́ ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí obìnrin kan tó máa ń kọrin àti ọkùnrin kan tó fẹ́ràn eré ìdárayá fi iṣẹ́ wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà.

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé​—Kí Ni Mo Fẹ́ Fi Ayé Mi Ṣe?​—Ìrírí (6:54)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ̀ sí i nípa ìdí tó fi yẹ kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà.

“Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ Fún Jèhófà?” (Ilé Ìṣọ́, January 15, 2010)

Wo fídíò orin yìí, kó o lè rí i pé àwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà máa ń láyọ̀.

Mo Fi Ayé Mi Fún Ọ (4:30)

Ka ìtàn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Ọ̀pọ̀ ọdún ni mo ti máa ń rò ó pé, ‘Kí nìdí tá a fi wà láyé?’” kó o sì kíyè sí ohun tó mú kí obìnrin kan ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó yẹ kó kà sí pàtàkì jù láyé ẹ̀.

“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, November 1, 2012)