Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 48

Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ

Fọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ

Àwọn ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ máa ń jẹ́ kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i tí nǹkan bá ń lọ dáadáa fún wa, wọ́n sì máa ń dúró tì wá nígbà ìṣòro. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn la lè mú lọ́rẹ̀ẹ́. Torí náà, báwo lo ṣe lè yan ọ̀rẹ́ gidi? Jẹ́ ká dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí.

1. Kí nìdí tó fi yẹ kó o ronú jinlẹ̀ kó o tó yan ọ̀rẹ́?

Tá a bá ń lo ọ̀pọ̀ àkókò pẹ̀lú ẹnì kan, ì báà jẹ́ pé a rí i sójú àbí a pàdé ẹ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, bó pẹ́ bó yá a máa fìwà jọ ẹni náà yálà ìwà ẹ̀ dáa àbí kò dáa. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ [àwọn tí ò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà] da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Tó o bá ní àwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀, wọ́n á jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, wọ́n á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa ṣe ìpinnu tó tọ́. Àmọ́ táwọn ọ̀rẹ́ wa ò bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n lè mú ká jìnnà sí Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi sọ fún wa pé ká máa fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ wa! Tí àwọn ọ̀rẹ́ wa bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n máa ràn wá lọ́wọ́, àwa náà sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìyẹn á jẹ́ ká lè ‘máa fún ara wa níṣìírí, ká sì máa gbé ara wa ró.’​—1 Tẹsalóníkà 5:11.

2. Báwo ni ìpinnu tó o bá ṣe nípa àwọn tó ò ń bá ṣọ̀rẹ́ ṣe kan Ọlọ́run?

Jèhófà kì í mú ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti rí lọ́rẹ̀ẹ́. “Àwọn adúróṣinṣin ni ọ̀rẹ́ Rẹ̀ tímọ́tímọ́.” (Òwe 3:32) Ṣé inú Jèhófà máa dùn tó bá jẹ́ pé àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ la mú lọ́rẹ̀ẹ́? Ó dájú pé inú ẹ̀ ò ní dùn! (Ka Jémíìsì 4:4.) Àmọ́, inú Jèhófà máa dùn sí wa, á sì sún mọ́ wa tá a bá ń ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti sún mọ́ ọn, tá a mú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́, tá a sì yẹra fún àwọn tí ò tẹ̀ lé òfin rẹ̀.​—Sáàmù 15:1-4.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìdí tó fi yẹ kó o fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àti bó o ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ gidi tó máa ṣe ẹ́ láǹfààní.

3. Ṣọ́ra kó o má bàa kó ẹgbẹ́ búburú

Ẹgbẹ́ búburú ni àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tí wọn ò sì tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Báwo la ṣe lè máa kó ẹgbẹ́ búburú láìfura?

Ka 1 Kọ́ríńtì 15:33, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn wo lo gbà pé ó lè jẹ́ ẹgbẹ́ búburú fún ẹ? Kí nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?

Ka Sáàmù 119:63, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn ìwà wo ló yẹ kí ẹni tó o máa mú lọ́rẹ̀ẹ́ ní?

Ápù kan tó ti bà jẹ́ máa kó èèràn ran àwọn tó kù. Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ tó o bá mú ẹnì kan tí kò nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́?

4. A lè rí ọ̀rẹ́ gidi láàárín àwọn tí ipò wọn yàtọ̀ sí tiwa

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n ń gbé ní Ísírẹ́lì àtijọ́, ìyẹn Dáfídì àti Jónátánì. Ọmọ ọba ni Jónátánì, ó sì dàgbà ju Dáfídì lọ dáadáa; síbẹ̀, ọ̀rẹ́ àtàtà lòun àti Dáfídì. Ka 1 Sámúẹ́lì 18:1, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tí kò fi pọn dandan kó jẹ́ pé àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́, àwọn tó lówó tàbí àwọn tó lẹ́nu láwùjọ nìkan ló yẹ ká mú lọ́rẹ̀ẹ́?

Ka Róòmù 1:11, 12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo làwọn ọ̀rẹ́ tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ṣe lè fún ara wọn níṣìírí?

Nínú fídíò yìí, wàá rí bí ọ̀dọ́kùnrin kan ṣe rí ọ̀rẹ́ níbi tí kò fọkàn sí. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, kí nìdí tí ọkàn àwọn òbí Akil ò fi balẹ̀ sáwọn tí Akil ń bá ṣọ̀rẹ́ nílé ìwé?

  • Kí nìdí tó fi kọ́kọ́ fẹ́ bá wọn ṣọ̀rẹ́?

  • Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti borí ẹ̀dùn ọkàn tó ní torí pé kò rẹ́ni bá ṣọ̀rẹ́?

5. Bó o ṣe lè ní ọ̀rẹ́ tòótọ́

Jẹ́ ká wo bó o ṣe lè ní ọ̀rẹ́ tòótọ́ àti​—bíwọ náà ṣe lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́. Wo FÍDÍÒ yìí.

Ka Òwe 18:24 àti 27:17, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Báwo làwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣe máa ń ran ara wọn lọ́wọ́?

  • Ṣé o ní ọ̀rẹ́ tòótọ́? Tó ò bá ní, kí lo lè ṣe láti ní?

Ka Fílípì 2:4, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tó o bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tòótọ́, ó yẹ kíwọ fúnra rẹ fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni ẹ́. Báwo lo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

Tó o bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ tòótọ́, ó yẹ kíwọ fúnra rẹ fi hàn pé ọ̀rẹ́ tòótọ́ ni ẹ́

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Ẹnikẹ́ni ni mo lè mú lọ́rẹ̀ẹ́, kò sóhun tó kàn mí bóyá ìwà ẹni náà dáa àbí kò dáa.”

  • Kí lèrò ẹ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tá a bá ń fọgbọ́n yan àwọn ọ̀rẹ́ wa, a máa múnú Jèhófà dùn, a sì máa ṣe ara wa láǹfààní.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tí ìpinnu tá a bá ṣe nípa àwọn tá a mú lọ́rẹ̀ẹ́ fi ṣe pàtàkì sí Jèhófà?

  • Irú àwọn èèyàn wo ni kò yẹ ká mú lọ́rẹ̀ẹ́?

  • Báwo la ṣe lè ní ọ̀rẹ́ tòótọ́ láàárín àwọn tó ń sin Jèhófà?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ka ìwé yìí kó o lè rí bí àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro.

“Ní Àjọṣe Tó Dáa Pẹ̀lú Àwọn Ará Kí Òpin Tó Dé” (Ilé Ìṣọ́, November 2019)

Kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn tó o bá fẹ́ yan ọ̀rẹ́ lórí ìkànnì?

Máa Fọgbọ́n Lo Ìkànnì Àjọlò (4:12)

Ka ìtàn tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Mò ń wá ẹni tí máa fi ṣe bàbá,” kó o sì kíyè sí ohun tó mú kí ọkùnrin kan ṣàyẹ̀wò irú àwọn tó ń mú lọ́rẹ̀ẹ́.

“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, April 1, 2012)