Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 57

Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Gan-an?

Kí Lo Lè Ṣe Tó O Bá Dá Ẹ̀ṣẹ̀ Tó Burú Gan-an?

Ó dájú pé o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe kó o má bàa rú òfin rẹ̀. Síbẹ̀, kò sí bó o ṣe lè ṣe é tó ò ní ṣàṣìṣe. Àmọ́, nígbà míì ohun tó o ṣe lè burú gan-an. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, rántí pé ìyẹn ò ní kí Jèhófà má nífẹ̀ẹ́ rẹ mọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ó ṣe tán láti dárí jì ẹ́, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.

1. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?

Inú àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń bà jẹ́ tí wọ́n bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an. Àmọ́, ìlérí tí Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ máa ń fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sọ pé: “Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tiẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, wọ́n máa di funfun bíi yìnyín.” (Àìsáyà 1:18) Jèhófà máa dárí jì wá pátápátá tá a bá ronú pìwà dà látọkàn wá. Báwo la ṣe lè ronú pìwà dà? A máa kábàámọ̀ ohun tá a ṣe, ìyẹn á mú ká jáwọ́ nínú ìwà tí ò dáa náà, àá sì bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá. Lẹ́yìn ìyẹn, àá ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè borí ohunkóhun tó mú ká hu ìwà tí ò dáa náà, àá sì gbìyànjú láti máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà nígbà gbogbo.​—Ka Àìsáyà 55:6, 7.

2. Báwo ni Jèhófà ṣe ń lo àwọn alàgbà láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dẹ́ṣẹ̀?

Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, Jèhófà sọ fún wa pé ká “pe àwọn alàgbà ìjọ.” (Ka Jémíìsì 5:14, 15.) Àwọn alàgbà yìí nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ àwọn ará. Torí náà, Jèhófà ti kọ́ wọn lóhun tí wọ́n máa ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú òun.​—Gálátíà 6:1.

Báwo làwọn alàgbà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an? Àwọn alàgbà méjì sí mẹ́tà máa fi Bíbélì tọ́ wa sọ́nà ká lè mọ̀ pé ohun tá a ṣe ò dáa. Wọ́n máa jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tá a lè ṣe ká má bàa hu irú ìwà yẹn mọ́, wọ́n sì máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè lókun pa dà. Wọ́n lè ní ká má ṣe lọ́wọ́ sí àwọn nǹkan kan nínú ìjọ títí tá a fi máa pa dà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Tẹ́ni tó dẹ́ṣẹ̀ náà ò bá ronú pìwà dà, àwọn alàgbà máa yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ kí wọ́n lè dáàbò bo ìjọ.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí Jèhófà ń ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, kó o lè túbọ̀ rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an.

3. Ara máa tù wá tá a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa

Ó máa ń dun Jèhófà gan-an tá a bá ṣe ohun tí kò dáa, torí náà a gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún un. Ka Sáàmù 32:1-5, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà dípò ká máa bò ó mọ́lẹ̀?

Lẹ́yìn tá a bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà, ó tún yẹ ká jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́ kí ara lè tù wá. Wo FÍDÍÒ yìí, kó o sì dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, báwo làwọn alàgbà ṣe ran Canon lọ́wọ́ kó lè pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà?

Ó yẹ ká sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fáwọn alàgbà, láìfi nǹkan kan pa mọ́. Ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́. Ka Jémíìsì 5:16, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Àǹfààní wo la máa rí tá ò bá fọ̀rọ̀ pa mọ́ fáwọn alàgbà?

Jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ ẹ fáwọn alàgbà láìfi ohunkóhun pa mọ́, kó o sì jẹ́ kí Jèhófà fìfẹ́ ràn ẹ́ lọ́wọ́

4. Àǹfààní tí gbogbo wa máa rí tí wọ́n bá yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ

Tẹ́nì kan bá dẹ́ṣẹ̀ tó burú gan-an, tó sì kọ̀ láti tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, kò sídìí tó fi yẹ kẹ́ni náà ṣì wà nínú ìjọ. Torí náà, wọ́n máa ṣe ìfilọ̀ fún ìjọ pé ẹni náà kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́, àwọn tó kù nínú ìjọ ò ní máa bá a kẹ́gbẹ́ mọ́, wọn ò sì ní máa bá a sọ̀rọ̀ mọ́. Ka 1 Kọ́ríńtì 5:6, 11 àti 2 Jòhánù 9-​11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Bó ṣe jẹ́ pé ìwúkàrà máa ń mú kí ìyẹ̀fun wú, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn ará ìjọ tí wọ́n bá ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí kò ronú pìwà dà?

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí ò rọrùn, ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n ti yọ kúrò nínú ìjọ ló ti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, tí wọ́n sì gbà pé bí wọ́n ṣe yọ àwọn ló ran àwọn lọ́wọ́ láti tún èrò àwọn ṣe. (Sáàmù 141:5) Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, àǹfààní wo ni Ṣadé rí torí pé wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú ìjọ?

Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan nínú ìjọ, báwo nìyẹn ṣe máa . . .

  • buyì kún orúkọ Jèhófà?

  • jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa àti pé ọlọ́gbọ́n ni?

5. Jèhófà máa dárí jì wá tá a bá ronú pìwà dà

Jésù sọ àpèjúwe tó jẹ́ ká mọ bó ṣe máa ń rí lára Jèhófà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá ronú pìwà dà. Ka Lúùkù 15:1-7, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ni àpèjúwe yìí jẹ́ kó o mọ̀ nípa Jèhófà?

Ka Ìsíkíẹ́lì 33:11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí la gbọ́dọ̀ ṣe ká lè fi hàn pé a ti ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

Bíi ti olùṣọ́ àgùntàn kan, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀, ọ̀rọ̀ wọn sì jẹ ẹ́ lógún gan-an

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò fẹ́ sọ ẹ̀ṣẹ̀ tí mo dá fáwọn alàgbà, kí wọ́n má bàa yọ mí kúrò nínú ìjọ.”

  • Kí lo lè sọ fún ẹni tó bá sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, àmọ́ tá a kábàámọ̀, tá a sì pinnu pé a ò ní hùwà náà mọ́, Jèhófà máa dárí jì wá.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa fún Jèhófà?

  • Kí ló yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ kí Jèhófà dárí jì wá?

  • Tá a bá dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ káwọn alàgbà ràn wá lọ́wọ́?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí ọkùnrin kan ṣe rí i pé aláàánú ni Jèhófà nígbà tí Jèhófà ṣe ohun tó wà nínú Àìsáyà 1:18 fún un.

Aláàánú Ni Jèhófà (5:02)

Tí wọ́n bá yọ ẹnì kan kúrò nínú ìjọ, àǹfààní wo nìyẹn máa ṣe fún gbogbo àwọn tọ́rọ̀ náà kàn?

“Ìdí Tí Ìyọlẹ́gbẹ́ Fi Jẹ́ Ìpèsè Onífẹ̀ẹ́” (Ilé Ìṣọ́, April 15, 2015)

Ka ìwé yìí kó o lè túbọ̀ mọ ìdí tá a fi ń yọ ẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀ kúrò nínú ìjọ, kó lè rọrùn fún ẹ láti ṣàlàyé fún ẹni tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Yẹra Fún Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Yín Mọ́?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Ka ìtàn yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí ọkùnrin kan gbà pé Jèhófà ló fa òun pa dà sínú òtítọ́. Àkòrí ìtàn náà ni “Mo Ní Láti Pa Dà Sọ́dọ̀ Jèhófà.”

“Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà” (Ilé Ìṣọ́, April 1, 2012)