Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 59

O Lè Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Táwọn Èèyàn Bá Tiẹ̀ Ń Ta Kò Ẹ́

O Lè Jẹ́ Adúróṣinṣin sí Jèhófà Táwọn Èèyàn Bá Tiẹ̀ Ń Ta Kò Ẹ́

Bó pẹ́ bó yá, gbogbo àwa Kristẹni la máa kojú inúnibíni. Ṣé ó yẹ kíyẹn dẹ́rù bà wá?

1. Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣenúnibíni sí wa?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ fi ayé wọn sin Ọlọ́run tọkàntọkàn ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi Jésù ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí.” (2 Tímótì 3:12) Àwọn èèyàn ṣenúnibíni sí Jésù torí pé kì í ṣe apá kan ayé. Àwa náà ò kì í ṣe apá kan ayé, torí náà kò yà wá lẹ́nu pé àwọn ìjọba ayé yìí àtàwọn ẹlẹ́sìn ń ṣenúnibíni sí wa.​—Jòhánù 15:18, 19.

2. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?

Àsìkò tá a wà yìí ló yẹ ká túbọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Rí i pé ò ń wáyè láti máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé, kó o sì máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. Máa lọ sí ìpàdé ìjọ déédéé. Àwọn nǹkan yìí á fún ẹ lókun, á sì jẹ́ kó o nígboyà láti kojú inúnibíni tàbí àtakò èyíkéyìí, kódà tó bá jẹ́ pé ìdílé rẹ ló ń ta kò ẹ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn ṣenúnibíni sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sọ pé: “Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù.”​—Hébérù 13:6.

Bákan náà, a máa túbọ̀ jẹ́ onígboyà tá a bá ń wàásù déédéé. Torí ṣe ni iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká túbọ̀ gbára lé Jèhófà, ìyẹn ò sì ní jẹ́ ká bẹ̀rù ẹnikẹ́ni. (Òwe 29:25) Tó o bá ti jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa fìgboyà wàásù báyìí, ó máa rọrùn fún ẹ láti máa wàásù táwọn ìjọba bá tiẹ̀ pàṣẹ pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù.​—1 Tẹsalóníkà 2:2.

3. Àwọn àǹfààní wo la máa rí tá a bá fara da inúnibíni?

Ó dájú pé ara kì í tù wá tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí wa, àmọ́ tá a bá fara da inúnibíni ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i. Ó máa ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, torí àá rí bó ṣe ń fún wa lókun láti máa fara dà á nígbà tó bá ṣe wá bíi pé a ò lókun mọ́. (Ka Jémíìsì 1:2-4.) Ó máa ń dun Jèhófà gan-an tá a bá ń jìyà, àmọ́ inú ẹ̀ máa ń dùn tó bá rí i pé a ò juwọ́ sílẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Tí ẹ bá fara da ìyà torí pé ẹ̀ ń ṣe rere, èyí dáa lójú Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:20) Tá a bá fara dà á dé òpin, Jèhófà máa fún wa láǹfààní láti wà ní ayé tuntun, níbi tí ẹnikẹ́ni ò ti ní máa ta ko ìjọsìn tòótọ́ mọ́, àá sì máa gbébẹ̀ títí láé.​—Mátíù 24:13.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo ohun tó jẹ́ ká mọ̀ pé a lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí wa, ká sì kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jèhófà ṣe máa bù kún wa tá ò bá juwọ́ sílẹ̀.

4. Fara dà á táwọn mọ̀lẹ́bí ẹ bá ń ta kò ẹ́

Jésù mọ̀ pé inú àwọn kan nínú ìdílé wa lè má dùn sí wa tá a bá pinnu pé a máa sin Jèhófà. Ka Mátíù 10:34-​36, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló ṣeé ṣe káwọn tó wà nínú ìdílé kan ṣe tẹ́nì kan nínú ìdílé náà bá pinnu láti sin Jèhófà?

Kó o lè rí àpẹẹrẹ kan, wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Kí ni wàá ṣe tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ ẹ kan bá ní kó o má sin Jèhófà mọ́?

Ka Sáàmù 27:10 àti Máàkù 10:29, 30. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo làwọn ìlérí tó wà nínú ẹsẹ yìí ṣe lè fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ táwọn mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ rẹ bá ń ta kò ẹ́?

5. Má fi Jèhófà sílẹ̀ táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí ẹ

A nílò ìgboyà tá a bá fẹ́ máa sin Jèhófà nígbà táwọn èèyàn bá ń ta kò wá. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Kí lo rí nínú fídíò yẹn tó jẹ́ kó o mọ̀ pé ìwọ náà lè jẹ́ onígboyà?

Ka Ìṣe 5:27-29 àti Hébérù 10:24, 25. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká pa ìjọsìn Jèhófà tì táwọn ìjọba bá tiẹ̀ sọ pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù tàbí lọ sí ìpàdé mọ́?

6. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́

Kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́mọdé àti lágbà jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà láìka ti pé àwọn èèyàn ń ṣenúnibíni sí wọn. Kó o lè rí ohun tó ràn wọ́n lọ́wọ́, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, kí ló ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin yẹn lọ́wọ́ láti fara dà á?

Ka Róòmù 8:35, 37-39 àti Fílípì 4:13. Lẹ́yìn tó o bá ka ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ẹsẹ Bíbélì náà, dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o lè fara da àdánwò èyíkéyìí?

Ka Mátíù 5:10-12, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló lè mú kó o máa láyọ̀ tó o bá tiẹ̀ ń kojú inúnibíni tàbí àtakò?

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti fara da inúnibíni àti àtakò. Ìwọ náà lè fara dà á!

ÀWỌN KAN SỌ PÉ: “Mi ò rò pé màá lè fara da inúnibíni.”

  • Ẹsẹ Bíbélì wo lo lè kà fún ẹni náà táá mú kó dá a lójú pé Jèhófà máa ràn án lọ́wọ́ kó lè fara da inúnibíni?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Jèhófà mọyì gbogbo ohun tá a bá ṣe ká lè máa sìn ín láìka ti pé àwọn èèyàn ń ta kò wá tàbí ṣenúnibíni sí wa. Ó máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á dé òpin.

Kí lo rí kọ́?

  • Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣenúnibíni sáwa Kristẹni?

  • Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe láti múra sílẹ̀ de inúnibíni?

  • Kí ló lè mú kó dá ẹ lójú pé o ò ní pa ìjọsìn Jèhófà tì táwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣenúnibíni sí ẹ?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Wo fídíò yìí kó o lè mọ bí Jèhófà ṣe ran ọ̀dọ́kùnrin kan lọ́wọ́ kó lè fara dà á nígbà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

Jèhófà Ràn Án Lọ́wọ́ Láti Fara Da Inúnibíni (2:34)

Wo ohun tó ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi tọkàntọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún láìka pé àwọn èèyàn ṣenúnibíni sí wọn.

Bá A Ṣe Sin Jèhófà Láwọn Àkókò Tí Nǹkan Ò Dẹrùn (7:11)

Ka ìwé yìí kó o lè mọ àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti jẹ́ onígboyà tí wọ́n bá ń ṣenúnibíni sí ẹ.

“Ìsinsìnyí Gan-An Ni Kó O Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ fún Inúnibíni” (Ilé Ìṣọ́, July 2019)

Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn tí ìdílé wa bá ń ṣenúnibíni sí wa, àwọn nǹkan wo la sì lè ṣe ká lè fara dà á láìfi Jèhófà sílẹ̀?

“Idà Ni Òtítọ́ Ń Mú Wá, Kì Í Ṣe Àlàáfíà” (Ilé Ìṣọ́, October 2017)