Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 60

Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà

Máa Ṣe Ohun Táá Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà

Látìgbà tó o ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìwé yìí, ó dájú pé o ti kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa Jèhófà. Ó ṣeé ṣe káwọn nǹkan tó o kọ́ yìí ti mú kó o nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an débi tó o fi ya ara ẹ sí mímọ́ fún un, tó o sì ṣèrìbọmi. Tó bá sì jẹ́ pé oò tíì ṣèrìbọmi, ó ṣeé ṣe kó o máa ronú pé wàá ṣèrìbọmi láìpẹ́. Àmọ́ ti pé ẹnì kan ṣèrìbọmi ò túmọ̀ sí pé kò ní máa ṣe àwọn nǹkan táá mú kó túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà mọ́. Títí láé ni wàá máa ṣe àwọn nǹkan táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Báwo lo ṣe lè máa ṣe bẹ́ẹ̀?

1. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa ṣe àwọn nǹkan táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

A gbọ́dọ̀ máa ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe ká lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀? ‘Ká má bàa sú lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ láé.’ (Hébérù 2:1) Àwọn nǹkan wo la lè máa ṣe tá a bá fẹ́ máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà? A lè máa lo àkókò tó pọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a sì lè ṣe àwọn nǹkan míì lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Ka Fílípì 3:16.) Ohun tó dáa jù lọ téèyàn lè fayé ẹ̀ ṣe ni pé kó sin Jèhófà!​—Sáàmù 84:10.

2. Àwọn nǹkan míì wo ló yẹ kó o máa ṣe?

Ní báyìí, o ti fẹ́ parí ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ nínú ìwé yìí, síbẹ̀ kò yẹ kó o dẹwọ́ láti máa ṣe àwọn nǹkan táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ máa “gbé ìwà tuntun wọ̀.” (Éfésù 4:23, 24) Torí náà, tó o bá túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tó o sì ń lọ sípàdé ìjọ déédéé, wàá máa kọ́ àwọn nǹkan tuntun nípa Jèhófà, wàá sì túbọ̀ máa mọ irú ẹni tó jẹ́. Ìyẹn á jẹ́ kó o máa wá bí wàá ṣe máa fara wé Jèhófà nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe. Bákan náà, wàá máa ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ nígbèésí ayé rẹ kó o lè máa múnú Jèhófà dùn.

3. Báwo ni Jèhófà ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run . . . máa fúnra rẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yín. Ó máa fún yín lókun, ó máa sọ yín di alágbára, ó sì máa fẹsẹ̀ yín múlẹ̀ gbọn-in.” (1 Pétérù 5:10) Gbogbo wa la máa kojú ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́. Àmọ́ Jèhófà ti fún wa ní ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ ká má bàa juwọ́ sílẹ̀. (Sáàmù 139:23, 24) Ó ṣèlérí fún wa pé òun máa mú kó wù wá láti ṣe ohun tó tọ́, òun sì máa fún wa ní agbára láti máa sin òun tọkàntọkàn.​—Ka Fílípì 2:13.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti túbọ̀ máa sún mọ́ Jèhófà àti bí Jèhófà ṣe máa bù kún ẹ.

4. Máa gbàdúrà déédéé, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́

O ti di ọ̀rẹ́ Jèhófà látìgbà tó o ti ń bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, tó o sì ń wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Báwo làwọn nǹkan yìí ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

Ka Sáàmù 62:8, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tó o bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àwọn àyípadà wo ló yẹ kó o ṣe nípa bó o ṣe ń gbàdúrà?

Ka Sáàmù 1:2 àti àlàyé ìsàlẹ̀, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Tó o bá fẹ́ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, àwọn àyípadà wo ló yẹ kó o ṣe nípa bó o ṣe ń ka Bíbélì?

Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ nígbà tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Kó o lè rí díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó o lè ṣe, wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Èwo nínú àwọn nǹkan tí wọ́n sọ nínú fídíò yẹn ni wàá fẹ́ ṣe?

  • Àwọn nǹkan wo ni wàá fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀?

5. Ronú nípa àwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà

Wàá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, wàá sì lè ṣe ìjọ láǹfààní tó o bá ní àwọn nǹkan pàtó tó wù ẹ́ láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Wo FÍDÍÒ yìí, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

  • Nínú fídíò yẹn, àǹfààní wo ni Cameron rí torí pé ó pinnu láti ṣe àwọn nǹkan pàtó kan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?

Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló lè lọ wàásù lórílẹ̀-èdè míì. Àmọ́ gbogbo wa la lè pinnu pé a máa ṣe ohun kan pàtó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ka Òwe 21:5, lẹ́yìn náà ronú nípa àwọn nǹkan tó o lè pinnu láti ṣe . . .

  • nínú ìjọ.

  • lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.

Báwo lẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó o ti pinnu láti ṣe?

Àwọn nǹkan tó o lè pinnu láti ṣe

  • Túbọ̀ máa gbàdúrà látọkànwá.

  • Ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.

  • Gbìyànjú láti mọ gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ yín.

  • Gbìyànjú láti ní ẹnì kan tí wàá máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé.

  • Ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tàbí aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

  • Tó o bá jẹ́ arákùnrin, gbìyànjú láti di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́.

6. Gbádùn ayé rẹ títí láé!

Ka Sáàmù 22:26, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe tó o bá fẹ́ gbádùn ayé rẹ ní báyìí àti lọ́jọ́ iwájú?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Máa ṣe àwọn nǹkan táá jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, kó o sì máa ronú nípa àwọn nǹkan pàtó tó o lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá gbádùn ayé rẹ ní báyìí àti títí láé!

Kí lo rí kọ́?

  • Kí ló mú kó dá ẹ lójú pé Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa fi gbogbo ọkàn rẹ sìn ín?

  • Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kó o lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

  • Tó o bá pinnu láti ṣe àwọn nǹkan pàtó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?

Ohun Tó O Lè Pinnu Láti Ṣe Láàárín Ọdún Kan

ṢÈWÁDÌÍ

Èwo ló ṣe pàtàkì jù sí Jèhófà nínú ká jẹ́ olóòótọ́ sí i lẹ́ẹ̀kan péré tàbí ká jẹ́ olóòótọ́ sí i jálẹ̀ ìgbésí ayé wa?

Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Bíi Ti Ábúráhámù (9:20)

Nígbà míì àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn lè má láyọ̀ mọ́. Wo fídíò yìí kó o lè mọ ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa fayọ̀ sin Jèhófà.

Wàá Láyọ̀ Tó O Bá Ń Kẹ́kọ̀ọ́ Tó O sì Ń Ṣàṣàrò (5:25)

Àwọn nǹkan wo lo lè pinnu láti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, báwo lo sì ṣe lè ṣe wọ́n láṣeyọrí?

“Fi Àwọn Ohun Tó Ò Ń Lé Nípa Tẹ̀mí Yin Ẹlẹ́dàá Rẹ Lógo” (Ilé Ìṣọ́, July 15, 2004)

Kí nìdí tó fi yẹ ká lóye àwọn ìlànà Bíbélì dáadáa, ká sì máa fi wọ́n sílò? Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

“Máa Tẹ̀ Síwájú Sí Ìdàgbàdénú Torí Pé ‘Ọjọ́ Ńlá Jèhófà Sún Mọ́lé’” (Ilé Ìṣọ́, May 15, 2009)