Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Mo Ti Múra Tán?

Ṣé Mo Ti Múra Tán?

Ṣé Mo Ti Múra Tán Láti Wàásù Pẹ̀lú Ìjọ?

O lè di akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi . . .

  • Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé, tó ò ń gbàdúrà, tó o sì ń lọ sípàdé ìjọ.

  • Tó o bá mọyì àwọn nǹkan tó ò ń kọ́, tó o gbà á gbọ́, tó sì wù ẹ́ láti máa sọ ọ́ fáwọn míì.

  • Tó o bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó o sì mú àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́.

  • Tó o bá ti kúrò nínú ẹ̀sìn èké, tó ò sì sí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú èyíkéyìí.

  • Tó o bá ń fi ìlànà Jèhófà sílò nígbà gbogbo, tó o sì fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Tó o bá gbà pé o ti múra tán láti máa wàásù, jẹ́ kí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀, á sọ fáwọn alàgbà kí wọ́n lè jẹ́ kó o mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe kó o lè bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù pẹ̀lú ìjọ.

Ṣé Mo Ti Múra Tán Láti Ṣèrìbọmi?

O lè ṣèrìbọmi . . .

  • Tó o bá ti di akéde tí ò tíì ṣèrìbọmi.

  • Tó o bá ń sa gbogbo ipá rẹ láti máa wàásù déédéé.

  • Tó o bá ń fara mọ́ àwọn ìtọ́ni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” bá fún wa, tó o sì ń tẹ̀ lé e.​—Mátíù 24:45-47.

  • Tó o bá ti gbàdúrà láti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà, tó o sì ṣèlérí fún un pé òun nìkan ni wàá máa sìn títí láé.

Tó o bá gbà pé o ti múra tán láti ṣèrìbọmi, jẹ́ kí ẹni tó ń kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ mọ̀, á sọ fáwọn alàgbà kí wọ́n lè jẹ́ kó o mọ àwọn nǹkan tó yẹ kó o ṣe kó o tó lè ṣèrìbọmi.