Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà


Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Púpọ̀ Látinú Ẹ̀kọ́ Bíbélì Yìí

Bó O Ṣe Lè Jàǹfààní Púpọ̀ Látinú Ẹ̀kọ́ Bíbélì Yìí

Kọ́kọ́ ka ìsọfúnni nípa ìwé yìí ní ojú ìwé yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e, lẹ́yìn náà kó o wo FÍDÍÒ yìí.

APÁ ÀKỌ́KỌ́

Tó o bá fẹ́ múra ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan sílẹ̀, kọ́kọ́ ka apá àkọ́kọ́. Àwọn ìbéèrè tá a fi àwọ̀ tó yàtọ̀ kọ (A) àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀ (B) á jẹ́ kó o dá àwọn kókó pàtàkì mọ̀. Kíyè sí i pé o tún máa ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan tá a kọ “ka” sí.

ÀÁRÍN

Ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ (D)  lábẹ́ Kẹ́kọ̀ọ́ Jinlẹ̀ jẹ́ àlàyé nípa ohun tó kàn. Àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ (E) sọ ohun tá a máa jíròrò. Olùkọ́ rẹ á sọ pé kó o ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan, wàá dáhùn ìbéèrè, wàá sì tún wo fídíò.

Tó o bá tẹ àwọn FÍDÍÒ tó wà nínú ìwé yìí lórí fóònù tàbí kọ̀ǹpútà, á gbé ẹ lọ síbi tí wàá ti rí fídíò tàbí àtẹ́tísí tó máa jẹ́ kí ẹ̀kọ́ náà túbọ̀ yé ẹ. Àwọn fídíò kan jẹ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ gangan. Àmọ́, ńṣe la kàn ń fàwọn míì ṣàpẹẹrẹ ohun tó lè ṣẹlẹ̀.

Fara balẹ̀ wo àwọn àwòrán, ka àlàyé wọn  (Ẹ), kó o sì ronú nípa bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà lábẹ́ Àwọn Kan Sọ Pé  (F).

APÁ TÓ GBẸ̀YÌN

Kókó Pàtàkì àti Kí Lo Rí Kọ́? (G) la fi parí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Kọ déètì tẹ́ ẹ parí ẹ̀kọ́ kọ̀ọ̀kan. Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe (GB) sọ àwọn ohun tó o máa ṣe fúnra rẹ. Ṣèwádìí (H) jẹ́ àfikún ìsọfúnni tó o lè kà tàbí tó o lè wò.

Bá a ṣe ṣètò ìwé yìí

Apá 1

Apá 2

Apá 3

Apá 4

Àlàyé Ìparí Ìwé

Bó o ṣe lè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì

Ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin (66) ló para pọ̀ di Bíbélì. Apá méjì ló pín sí: Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ati Árámáíkì (“Májẹ̀mú Láéláé”) àti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì (“Májẹ̀mú Tuntun”).

Nínú ìwé yìí, tá a bá tọ́ka sí ibì kan nínú Bíbélì, orúkọ ìwé Bíbélì ló máa ń ṣáájú (A), orí Bíbélì ló máa ń tẹ̀ lé e (B), lẹ́yìn náà ẹsẹ tàbí àwọn ẹsẹ (D).

Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù 17:3 tọ́ka sí ìwé Jòhánù, orí 17, ẹsẹ 3.